Code of Conduct Tribunal: Adájọ́ Àgbà Nàíjíríà, Walter Onnoghen ní ẹjọ́ láti rò

ONNOGHEN Image copyright Google
Àkọlé àwòrán Ìjọba àpapọ̀ fi ẹ̀sùn ìwà ìbàjẹ́ àti pípa irọ́ lóri ohun ìnì Walter Onnoghen láti ìgbà tí ó jẹ Adájọ́ Agba lórílẹ̀èdè Naijria.

Ile ẹjọ to n gbẹjọ iwa ibajẹ, ti ni dandan ni Adajọ Agba Naijiria, Walter Onnoghen ni ẹjọ lati ro lori ẹsun irọ pipa ti wọn fi kan an.

Ile ẹjọ CCT onijoko mẹta ti adajọ Danladi Umar se adari fun sọ eyi lẹyin ti Onnoghen pe ẹjọ wi pe oun o lẹjọ iwa ibajẹ kankan.

Ajọ naa wa pa se pe Onnoghen gbọdọ wa ro ti ẹnu rẹ lori ẹsun irọ pipa lori ohun ini rẹ.

Ile ẹjo naa wa sun igbẹjọ naa si Ọjọ Aje, ki Onnoghen fi le raye wa wi ti ẹnu rẹ lori ẹsun ti ijọba apapọ fi kan an.