Ethiopian Airlines crash: Awakọ̀ òrúrufú pariwo 'lọ sókè! lo sókè!' kí ó tó já

Awakọ̀ òrúrufú Ethiopian Airlines Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Awakọ̀ òrúrufú Ethiopian Airlines pariwo lọ sókè! lo sókè!

Iroyin ti n jade lori bi ọkọ ofurufu Ethiopian Airlines to gbe eniyan mẹtadinlọgọjọ se jabọ to si pa gbogbo eniyan to wa ninu rẹ lọse mẹta sẹyin.

Iwe Iroyin Wall Street Journal gbe jade wi pe ọkan lara awọn awakọ naa pariwo ki awakọ baalu naa lọ soke, ko lọ soke, ki o ma ba a da ẹnu kọlẹ bi ose n se mọ.

Ẹrọ igbalode ti ko ni jẹ ki ọkọ ofurufu o duro lojiji loju ọrun Boeing 737 Max ni awọn oniwadii sọ wi pe o seese ko se okunfa iku awọn to wa ninu ọkọ baalu wọn.

Isẹju mẹfa ti ọkọ naa gbera kuro lati papakọ ofurufu Addis Ababa lọ si Nairobi ni orilẹede Kenya lo ja.