Premier League: Man City ti fàgbà han Fulham pẹ̀lú 2-0

Man City Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Man City ti fàgbà han Fulham pẹ̀lú àmì ayò méjì sódo nínú ìlépa rẹ̀ láti gba ife Ẹyẹ Premiership tọdún yìí.

Ẹgbẹ agbabọọlu Manchester City ti wa loke tente idije Premier League lẹyin ti wọn na ẹgbẹ agbabọọlu Fulham pẹlu ami ayo meji sodo.

Ẹlẹẹkẹjọ ni yii ti Fulham yoo ma fidi rẹmi ninu idije Premier League ti saa yii.

Sergio Aguero ati Bernado Silva lo gba bọọlu naa wọnu awọn, to si mu ki Manchester City bori ninu ifẹsẹwọnsẹ naa.

Bakan naa ni Leicester City naa Huddersfield pẹlu ami ayo meji si ẹyọkan.

Crystal Palace naa gbena woju Bournemouth pelu ami ayo meji si eyokan.