Mother's day: Ka àwọn ìròyìn tí BBC News Yorùbá tí ṣe fún ìdàgbàsókè àwọn obìnrin

Iya kan n lọ ata Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Àyájọ́ àwọn ìyá lórílẹ̀èdè Nàìjíríà ń wáyé lónìí

Ọpọ nnkan ni oju obinrin n ri lawujọ. Ileeṣẹ iroyin BBC News Yoruba ti ṣe ọpọlọpọ iroyin nitori awọn obinrin-imuṣẹ alaa wọn, idagbasoke ati ilepa wọn lawujọ.

Eyi ni diẹ lara awọn iroyin naa ti BBC News Yoruba ti ṣe lati fi gbe awọn obinrin larugẹ ati lati mu ipenija wọn jade wa si ita gbangba.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionNeha Sharma: obìnrin tó ń múra bíi ọkùnrin láti leè ṣiṣẹ́ gẹrígẹrí

Rape: Oluwaseun Osowobi ní Commonwealth fún lámì ẹ̀yẹ ọ̀dọ́ tó pegedé jùlọ ní 2018

Àkọlé àwòrán Rape: Oluwaseun Osowobi ní Commonwealth fún lámì ẹ̀yẹ ọ̀dọ́ tó pegedé jùlọ ní 2018

Oluwaseun Osowobi la laalaa ifipabanilopọ kọja lati di ajafẹtọ awọn ti wọn ti la iru iṣẹlẹ bẹẹ kọja.

Ni orilẹede bii Naijiria nibi ti o jẹ iṣoro fun obinrin lati sọrọ bi wọn ba fi ipa baa lo pọ, Seun ba BBC News Yoruba sọrọ lori ipenija rẹ atawọn obinrin miran lori iwa buruku yii.

Ẹ woo nibi: https://www.bbc.com/yoruba/afrika-47703184

Sẹ́gílọlá: Arúgbó awẹ́lẹ́wà tó ń ṣiṣẹ́ omidan

Àkọlé àwòrán Sẹ́gílọlá: Arúgbó awẹ́lẹ́wà tó ń ṣiṣẹ́ omidan

Sẹgilọla, jẹ iya agba ti ọjọ ori rẹ ti le ni aadọrin. Bi o tilẹ jẹ pe ọjọ ori ti lọ lara iya'ṣugbọn ẹwa iya ko lọ.

Ni asiko ti a n ri ọpọlọpọ awọn arugbo ni igboro ti wọn n ṣagbe, a ri iya ti ọkan lara awọn ọmọ rẹ woo pe ẹwa rẹ ṣi lee ṣe anfani fun awujọ ati iwuri fun ọpọ awọn obinrin lode oni.

Ẹ ka itan arabinrin Abimbọla Ọlayinka, arugbo to n ṣe iṣẹ omidan nibi: https://www.bbc.com/yoruba/afrika-47649104

Ìwà ipá nínú ìdílé máa ń bí ìgè àti àdùbí ni tó lè já sí ikú

Àkọlé àwòrán Ìwà ipá nínú ìdílé máa ń bí ìgè àti àdùbí ni tó lè já sí ikú

Lode oni, ọpọ idile ni iwa ipa ti n ṣẹlẹ. Yatọ si pe ọpọ obinrin ni o n jẹ iya lilu lọwọ ọkọ, iwa ipa ninu idile kọja ki ọkọ o gbe ọwọ soke lu iyawo rẹ. Ara awọn iwa ipa ni ki ọkọ maa foro ẹmi iyawo ni ile, ki ọkọ maa fi orun adidun jẹ iyawo rẹ niya ati bẹẹbẹẹ lọ.

Gbogbo eyi naa ni BBC News Yoruba gbe yẹwo ninu iroyin ijiroro itagbangba yii to pe akori rẹ ni 'Ìwà ipá nínú ìdílé máa ń bí ìgè àti àdùbí ni tó lè já sí ikú'

Ẹ wo ẹkunrẹrẹ rẹ nibi: https://www.bbc.com/yoruba/46733903

Mọrèmi: Ọọ̀ni ní láìsi Mọrèmi, kò leè sí ilẹ̀ Yorùbá

Àkọlé àwòrán Mọrèmi: Ọọ̀ni ní láìsi Mọrèmi, kò leè sí ilẹ̀ Yorùbá

Iroyin yii da le ipa ti obinrin ko ninu ominira ati idagbasoke ọpọ awujọ lagbaye. BBC News Yoruba lo Moremi gẹgẹ bii apẹrẹ.

Ẹ lọ kaa nibi: https://www.bbc.com/yoruba/afrika-46744382

Kádàrá ní ọ̀rọ̀ ẹ̀dá láyé, Mo gbà pé Ọlọrun ló kọ ikú ọkọ mi ni Saudi

Àkọlé àwòrán Kádàrá ní ọ̀rọ̀ ẹ̀dá láyé, Mo gbà pé Ọlọrun ló kọ ikú ọkọ mi ni Saudi

Yetunde Raji jẹ obinrin ti igbe aye rẹ yi pada si bi ko ṣe lero lẹyin ti oun ati ọkọ rẹ wa ninu ijamba ọkọ to waye ni orilẹede Saudi Arabia.

Omije n bọ loju arabinrin Yetunde Morẹnikeji Raji ṣugbọn o ni omije ayọ ni.

Ẹ lọ ka itan yii ni: https://www.bbc.com/yoruba/45319192

Omi titun ti rú nínú oríṣii ètò ìgbéyàwó Yorùbá lásìkò yí

Àkọlé àwòrán Omi titun ti rú nínú oríṣii ètò ìgbéyàwó Yorùbá lásìkò yí

Ṣe wọn ni ibi gbogbo ni ifẹ wa bi a ba lee farabalẹ waa. Eyi ni iroyin itan ọmọ orilẹede Naijiria kan to ri ifẹ ni orilẹede Kẹnya. BBC News Yoruba kuku tẹlee debẹ lati mọ ohun gan to ri lọbẹ to fi wa ro ọwọ.

Ẹ ka nipa oun pẹlu nibi: https://www.bbc.com/yoruba/afrika-46577202

#67yearoldmother: Mo kojú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àìsàn fún ọdún 35 lẹ̀yín ìgbéyàwò

Àkọlé àwòrán #67yearoldmother: Mo kojú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àìsàn fún ọdún 35 lẹ̀yín ìgbéyàwò

Iyi ati idunnu nla ni o maa n jẹ fun obinrin lati ṣe igbeyawo ki o si lọmọ. Fun Dokita Ogunfunmilayọ, ayọ yii pẹ pupọ fun un nitori o pe ọmọ ọdun mẹtadinlaadọrin, 67 ki o to rọmọ bi.

Ki ẹ to ṣe haa, ẹ lọ ka ọpọ iyanu miran ti o wa ninu ọrs iyaafin ogunfunmilayọ ninu iroyin BBC News Yoruba yii: https://www.bbc.com/yoruba/46008107

Ìlú Igbo-Ọra: Ijọba ipinlẹ Ọyọ ṣe ayẹyẹ ọdun ibeji fún ìgbà àkọ́kọ́

Àkọlé àwòrán Ìlú Igbo-Ọra: Ijọba ipinlẹ Ọyọ ṣe ayẹyẹ ọdun ibeji fún ìgbà àkọ́kọ́

Ilu igboọra jẹ ilu kan lagbaaye to gbajugbaja fun ọwọja ibi ibeji nibẹ. Ọdọọdun si ni wọn maa n ṣe ajọyọ fawọn ibeji nibẹ.

Ṣe ko kuku si obinrin ti yoo gbọ ọrọ ọmọ ti ko ni ta kiji, eyi lo si gbe BBC News Yoruba de Igboọra lati mọ aṣiri ibi ibeji nibẹ.

Ẹ kaa nibi: https://www.bbc.com/yoruba/afrika-45851939

Ogundiya: Àṣìṣe Dókítà ló sọ mi di aláàbọ̀ ara lórí kẹ̀kẹ́

Àkọlé àwòrán Ogundiya: Àṣìṣe Dókítà ló sọ mi di aláàbọ̀ ara lórí kẹ̀kẹ́

Ọtọ ni aisan ti omidan Ṣeun Ogundiya ba lọ si ileewosan, ọtọ ni oogun ti wọn fun, aile gbe ẹsẹ lo ba kuro ni ileewosan.

Ki wa ni ipenija rẹ. Ẹ lọ woo nibi: https://www.bbc.com/yoruba/afrika-45109762

Ìyá ìbarùn-ún: Mo rò pé 'scan' ń pa irọ́ niní oyún pé márùn-ún ni màá bí

Àkọlé àwòrán Ìyá ìbarùn-ún: Mo rò pé 'scan' ń pa irọ́ niní oyún pé márùn-ún ni màá bí

Pẹlu bi nnkan ṣe ri ni ilu bayii, ọpọ ni ko fẹ bimọ mọ. Eyi lo mu ki itan tọkọtaya Imudia paapaajulọ arabinrin Oluwakẹmi Uduehi to bi ọmọ marun lẹẹkan ṣoṣo.

BBC News Yoruba kuku waa lọ lati gboṣuba fun awọn iya lori ipenija itọju ọmọ.

Ohun ti a ba bọ nigba naa niyi: https://www.bbc.com/yoruba/afrika-45028252

Ẹ tun lee wo awọn iroyin miran to jẹ mọ idagbasoke obinrin ni ibi:

  • Ìran kan si ìkejì ló n gbèrò láti ṣe ìgbéyàwo àjùmọ̀ṣe 'Shao' fọ́mọ wọn

https://www.bbc.com/yoruba/46285924

  • Akinọla: Ọdún méjì ni kí ẹ ti bẹ̀rẹ̀ kíkọ́ ọmọ nípa ìbálòpọ̀:

https://www.bbc.com/yoruba/46176740