Àwọn wo ni gómìnà mẹ́rin tí yóò kojú àjọ EFCC lẹ́yìn tí wọ́n bá kúrò nípò?

Image copyright EFCCofficial
Àkọlé àwòrán Ajọ EFCC nmi to awon yoo se iwadii finifini

Kẹ̀rẹ̀ kẹ̀rẹ̀ bi àwọn aláṣẹ ijọba tuntun ti wọn dibò yàn yoo ṣe fẹ gba ijọba, àjọ to ri sí ìwà jẹudujẹra (EFCC) ti pari ètò láti bẹ̀rl ìwádìí àwọn gomínà ti wọn fẹsun kan pe wọn ṣe owo ilú maku-maku.

O kéré tán ìpínlẹ̀ méjìlá ni yóò gba gómina túntún ní ọjọ kọkandinlọgbọ̀n oṣù karun ti sáà tó n bẹ lóde yìí ba wá sópin.

Awọn ìpínlẹ̀ náà ní Lagos, Ogun, Oyo, Imo, Kwara, Nasarawa, Yobe, Borno, Adamawa, Bauchi, Gombe àti Zamfara, ẹ̀wẹ̀ nínú àwọn ìpínlẹ̀ méjìlá yìí mẹ́rin nínú àwọn gómìnà náà ni wọn ti na ìka àlébù si pé wọn ṣe ol'w ìlú mọ́ku-mọ̀ku,

Àwọn gómìnà ọ̀hún ni Rochas Okorocah ti ipínlẹ̀ Imo, Abdulfatah Ahmed ti ìpínlẹ̀ Kwara, alága àwọn ẹgbẹ́ gómìnà tó tún jẹ gómìnà ìpínlẹ̀ Zamfara Abdulaziz Yari àti gómìnà ìpínlẹ̀ Ogun Ibikunle Amosun.

Àjọ EFCC ní sáájú òhún ti mú onisiro owo ìpínlẹ̀ Imo Uzoho Casmir fún ríràn Okorocha lọ́wa láti jí owó tó to bílíọnù kan Naira kó lásiko ìdìbò gómìnà àti ilé ìgbìmọ asofin.

Ní Zamfara àjọ EFCC ń sewadìí Yari fún dídari owo to tó biliọnu naira, Saááju ni ile ẹjọ kan l'Abuja ti gbésẹ̀ lé ẹ̀ẹ̀dẹ́gbẹ̀ta mílíọnù naira lọdun 2017, owo ti wọn ji ko ninu owo paris club ti ijọba apapọ fún àwọn ìpínlẹ̀ mẹ́rìndinlógóji Nàìjíríà.

Owó ọ̀hún ní wọn ni wọn ri ni àwọn ile iṣẹ́ méji kan tó wọn si tọpasẹ̀ rẹ̀ dé ọ̀dọ gómìnà Yari.

Gónìmà Abdulfatah náà yóò káwọ pọ̀nyin rojọ́ lọ́dọ̀ àjọ EFCC lẹ́yìn to ba pari sáà rẹ̀, Abdulrahaman Abdulrazak ti wọn ṣẹ̀ṣẹ̀ dìbò yàn náà ti ni gbogbo kúlẹ̀ kúlẹ̀ gómìnà ni òhun yóò tú wo ní kete to ba ti kúro lóri oyè.

Sááju nínú osù yìí àjọ EFCC ti mú àwọn kọmisọnà mẹ́fà àti àti àwọn aláṣẹ ijọba ní ìpínlẹ̀ Kwara nítori wọn dari owo to to bílíọ̀nu kan náírà sí ọ̀nà ìbòmiran ńgbà ti ók u ọsẹ̀ kan ti ìdìbò ààrẹ àti ti ilé ìgbìmsọ̀ asofin àgbà yóò wáye

Ní ti Amosun, ìwádìí tirl kò ṣẹ̀yìn ìwé ẹsun ti àwọn ẹgbẹ́ kan ti a mọ si Committee for the protection of Peopl's Mandate kọ ránṣẹ́ lóri bi Amosun ṣe ṣe bílíọ̀nu mẹ́rìn naira owo àwọn àgbe ní ìpínlẹ̀ Ogun mọ́ku-mọ̀ku