9th Assembly: Gbajabiamila fi èróńgbà rẹ̀ láti jẹ adarí ilé aṣojú ṣòfin hàn

Femi Gbajabiamila Image copyright Facebook/Femi Gbajabiamila
Àkọlé àwòrán Ibo ile aṣoju ṣofin

Aṣoju ṣofin Femi Gbajabiamila ti kede erongba rẹ lati jẹ adari ile aṣofin agba l'Abuja.

Gbajabiamila to jẹ olori ẹgbẹ oṣelu to pọ julọ nile aṣoju ṣofin fọrọ naa lede lọjọ Aiku nilu Abuja lẹyin ọjọ meji tẹgbẹ oṣelu rẹ APC ṣepade lori ẹni ti wọn fẹ ṣatilẹyin fun lati dari ile.

Ọgọsan aṣoju ṣofin lo wa nibi ti Gbajabiamila ti kede erongba rẹ niluu Abuja.

Gbajabiamila sọ pe oun yoo ṣakitiyan lati ri wi pe awọn aṣofin ṣe ofin lati jẹ ki awọn ọmọ orilẹede Naijiria gbaye gbadun ti ile ba yan oun gẹgẹ adari.

Ninu ọrọ tirẹ, olori ipolongo fun Gbajabiamila, aṣoju ṣofin Mumin Jibrin ni Gbajabiamila lo to gbangba sun lọyẹ lati jẹ adari ile aṣoju ṣofin l'Abuja.

O ni oun lo ni ọpọlọpọ iriri, ọgbọn ati imọ lati tukọ ile aṣofin.