Xenophobic Attacks: Ìjọba South Africa ní k'áwọn agbófinró ṣisẹ́ wọn bíi iṣẹ́

Ikoriira ni South Afrca Image copyright Getty Images

Minisita fun ọrọ ilẹ okere lorilẹede South Africa Lindiwe Sisulu ti pepade pajawiri pẹlu awọn aṣoju orilẹede miran lẹyin ti awọn ọmọ ilẹ South Africa kan ṣeku pa awọn ọmọ ilẹ okere.

Ẹsun awọn ọmọ ilẹ South Africa fi kan awọn ọmọ ilẹ okere ni pe wọn n gbaṣẹ awọn ṣe.

Lọjọ Aje to ọsẹ to lọ, eeyan mẹta lo padanu ẹmi wọn nigba ti awọn ọmọ ilẹ South Africa n fi ẹhonu han ti wọn si ba ọpọlọpọ sọọbu to jẹ tawọn eeyan ilẹ okere jẹ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionÈré Ọṣun: Àtáója ní wọn kò jí ère Ọṣun, ó sì wà níbi tó wà

Ko da awọn bi aadọta eeyan lo sa asala lọ si ago ọlọpaa nigba tawọn ọmọ ilẹ South Africa doju ija kọ wọn lọganjọ oru.

Obinrin ṣagbako iku nibi ti o ti sa fun ọwọn ọmọ onilẹ ti wọn n fẹhonu han.

Awọn meji miran ku lẹyin ti ẹnikan fun wọn

Minisita Sisulu sọ pe ijọba ko faye gba iru iwa bẹẹ, bakan naa lo ke si awọn agbofinro lati mu awọn to n da wahala silẹ.

Image copyright AFP

Ko da ọjọ Aje ni yoo ba minisiat naa yoo bawọn aṣoju orilẹede ṣepade.

Eeyan meje lo ku lọdun 2015 nigba ti iru ija ẹlẹyamẹya bayii ṣẹlẹ niluu Johannesburg ati Durban.

Eleyi to buru julọ ṣẹlẹ lọdun 2008 nibi ti ọgọta ọmọ ilẹ okere ti padanu ẹmi wọn lorilẹede South Africa.