#EndSARS: Ìbọn ba Kolade Johnson níbi tó tí ń wo bọ́ọ̀lù

Ọlọpaa SARS Image copyright PoliceEN_PCRRU/Twitter

Ariwo ẹ fopin si ọlọpaa SARS lo gba oju ayelujara kan lori ẹsun ti wọn fi awọn ọlọpaa ọhun pe wọn yinbọn pa ọmọkunrin kan ti orukọ rẹ jẹ Kolade Johnson lagbegbe Onipẹtẹsi niluu Eko lọjọ Aiku.

Iroyin to tẹ wa lọwọ sọ pe ọmọkunrin yii n wo ifẹsẹwọnsẹ laarin Liverpool ati Tottenham lori ẹrọ amohunmaworan lọwọ nile ounjẹ igbalode kan nigba ti awọn ọlọpaa SARS ya bo ibẹ ti wọn si dabọn bo lẹ.

Iroyin ni nibi ti wọn ti n yinbọn lai nidi kan pato ni ọta ibọn ba Kolade lori ijoko rẹ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionColorado ni Amẹrika àti odò Awaye ní Naijiria nikeji àdágún órí àpáta ní gbogbo àgbáyé!

Ẹni ti ọrọ naa ṣoju rẹ ṣalaye pe awọn ọlọpaa SARS mu ọrẹ Kolade to di oloogbe ni Kolade ba beere lọwọ wọn wi pe ki lo de ti wọn fi mu ọrẹ.

Lẹyin naa ni ọkan lara awọn ọlọpaa naa ba yinbọn fun un, wọn gbe Kolade digbadigba lọ sile iwosan ṣugbọn ẹpa ko boro mọ.

Agbẹnusọ fun ile iṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Eko Bala Elkana sọ pe awọn yoo iwadii lori iṣẹlẹ ọhun.

Ọpọ lo bu ẹnu ẹtẹ lu iṣẹlẹ naa loju opo Twitter ti gbogbo wọn si fohun sọkan pe ki wọn ọlọpaa SARS nilẹ lo dara.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionAAUA; Ọ̀pọ̀ ìgbà ni SARS ma ń lu àwọn akẹ́kọ̀ọ́ fásitì wa

Iṣẹlẹ naa lo mu awọn ọdọ kan binu di oju ọna marosẹ Eko si Abeokuta ti eleyi si fa sunkẹrẹ fakẹrẹ loju popo lọjọ Aiku.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionSARS ti bẹ̀rẹ̀ ìgbésẹ̀ láti yọ àwọn ọ̀bàyéjẹ́ kúro