Nnamdi Kanu: Mo lè dá wàhálà sílẹ̀ ní Nàíjíríà, tí ìjọba bá bími nínú

Nnamdi Kanu Image copyright Elliot Ugochukwu-Ukoh
Àkọlé àwòrán Opo igba ni Kanu ti ṣeleri pé oun to dari Biafra ti iran Igbo ba ya kuro lara Naijiria

Awọn ọmọ Naijiria ti fesi si ọrọ ti adari awọn to n ja fun idasilẹ orilẹ-ede Biafra, Nnamdi Kanu sọ.

Kanu sọ ọrọ yii lati kilọ fun ijọba apapọ lati ma ṣe ohunkohun ti yoo mu inu bi oun nitori oun le jẹ ki orilẹ-ede Naijiria gbona.

Bi awọn miran ṣe n gboriyin fun ọrọ ti Kanu Nnamdi sọ yii, ni awọn miran n bu ẹnu ẹ̀tẹ́ lu ọrọ to fi lede lasiko to n ba awọn ọmọ ilẹ Biafra sọrọ lati ilu London, ni Ile Gẹẹsi.

Kanu ni ijọba apapọ nigba tó n lo ile ẹjọ giga to wa ni Abuja lati gbẹṣẹ le aṣẹ ti o fun oun ni beeli tẹlẹ, ṣugbọn ti wọn ti yii pada ba yii lati fi panpẹ ọba mu oun, nipa lilo awọn ọlọpaa agbaye, eyi to jasi pabo.

Adari awọn to n ja fun idasilẹ orilẹ-ede Biafra naa fikun wi pe, ki ijọba apapọ ko ṣe ifẹ inu wọn o, ati wi pe ọmọbibi Ilẹ Gẹẹsi ni oun, ti ko si ẹ ni to le ṣe oun basubasu.

Lara awọn ọmọ Naijiria to jẹ alatilẹyin fun Nnamdi Kanu fesi si ọrọ naa lọri oju opo ikansiraẹni Twitter, ti wọn si gboriyin fun ipa ti Nnamdi Kanu nko lati mu iyipada ba aye awọn alatilẹyin rẹ.

Nigba ti awọn miran sọ wi pe ariwo lasan ni Kanu n pa, ati wi pe ọrọ rẹ kii se oun ti awọn ọmọ Naijiria ye ki wọn fesi si.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionColorado ni Amẹrika àti odò Awaye ní Naijiria nikeji àdágún órí àpáta ní gbogbo àgbáyé!