Wo ohun tó ṣẹlẹ̀ nilẹ̀ Adulawọ lọṣẹ tó lọ

A ni ki a fi eleyi ṣe moriwu fun yin nibẹrẹ oṣu tuntun ki a si ma gbagbe awọn ohun to ṣẹlẹ lọsẹ to pari oṣu ti a lo tan.

Diẹ ree ninu akojọpọ awọn awọran manigbagbe lati ilẹ Áfríkà lose to kọja fun igbadun yin.

Image copyright AFP
Àkọlé àwòrán Awọn eeyan ti iji Cyclone Idai ṣe akoba fun ko tii bọ lẹyin iṣẹlẹ ọhun. Awọn obinrin wọnyi ni Mozambique n to lati gba nnkan eelo lọjọ Iṣẹgun to kọja.
Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Iya n ronu; ọmọ n roka lo ri ni Mozambique. Bi awọn iya ti ṣe n to lawọn ọmọdebinrin wọnyi n ṣa ododo nibi awọn ile ti o wo ni ilu Beira lọjọ Aiku.
Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Jangilofa epo mọtọ! Nilu ti iji ti sọṣẹ niṣe ni awọn ọmọkunrin wọn yi n ṣere lori igi agbọn ti iji wo lọjọru
Image copyright AFP
Àkọlé àwòrán Lorile-ede Kenya, awọn akẹkọọ da muso fun olukọ wọn ni papakọ ofurufu Kenya nigba to dari lati ibi ti o ti gba ẹbun $1m (miliọnu dọla kan) gẹgẹ bi olukọ to pegede julọ lagbaye
Image copyright @ProfOsinbajo
Àkọlé àwòrán Igbakeji aarẹ Naijiria ati iyawo rẹ, Dolapo Osinbajo nibi ayẹyẹ isin idupe lẹyin ti wọn wọle gẹgẹ bi igbakeji aarẹ nidibo Naijiria tó kója nilu Ikenne, ipinlẹ Ogun
Image copyright AFP
Àkọlé àwòrán Lọjọ Aiku, alatilẹyin ẹgbẹ agbabọọlu Zimbabwe yi n dawọ idunnu bi ikọ rẹ ti ṣe fi ami ayo 2-0 sagba Congo-Brazzaville ninu ifẹsẹwọnsẹ lati kopa ninu idije Africa Cup of Nations
Image copyright Reuters
Àkọlé àwòrán Lọjọ Abamẹta, ajagunfẹyinti orile-ede Ethiopia yi n fẹsẹ rajo nibi ayẹyẹ kan ti wọn ṣe lati fi gba alejo irun ori Emperor Tewodros II ti ile iṣẹmbaye ilẹ Gẹẹsi, National Army Museum da pada si Ethiopia
Image copyright AFP
Àkọlé àwòrán Lọjọ keji, oludibo yi n yẹ orukọ rẹ wo loju patako lati le kopa ninu idibo aarẹ Comoros Islands
Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Fọfọ ni igboro Algiers kun nibi iwọde to waye lọjọ Eti. Awọn eetan orile-ede naa fẹ ki aarẹ Abdelaziz Bouteflika kọwe fipo silẹ
Image copyright EPA
Àkọlé àwòrán Titi di ọjọ Ajẹ awọn eeyan Algeria ko dawọ iwọde naa duro