Fiditi: Àwọn olùgbé rawọ ẹbẹ sí ìjoba lẹ́yìn tí ìjì ṣí òrùlé mọ́ wọn lórí

Aworan awọn ile ti atẹgun ojo si lọ ni Fiditi

Awọn olugbe ilu Fiditi nipinlẹ Ọyọ ti rawọ ẹbẹ si ijọba lori akoba ti atẹgun ojo ṣe fun ọpọlọpọ ile ninu ilu naa lọjọ Abamẹta.

Lasiko ti ikọ iroyin BBC Yoruba ṣe abẹwo si ilu naa, pupọ ninu awọn olugbe ilu naa ni wọn ti di asunta nitori airi'le gbe.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionỌ̀nà ọ̀fun lọ̀nà ọ̀run - omi ò jẹ́ ká ta ọjà

Botilẹ jẹ wi pe ẹmi ẹnikẹni ko ba iṣẹlẹ naa lọ, ọpọlọpọ dukia lo ṣofo, bẹẹ sini awọn ibusun ati aga ijoko di sisa sinu oorun.Lara awọn olugbe ilu naa ti o ba ikọ BBC Yoruba sọrọ ṣe alaye wi pe ṣa dede ni atẹgun ojo ka ile mọ awọn lori lọjọ Abamẹta, ti ọrọ naa si di boolọ-o-yago fun mi.Wọn ke si ijọba ipinlẹ Ọyọ lati daṣọ ro wọn lori awọn orule ti atẹgun ojo ṣi lọ.Botile jẹ wi pe awọn olugbe kan ti n ṣe atunṣe orule wọn, awọn kan ṣi wa ni gbayawu.