World Autism Day:Ẹ̀bùn ni ọmọ mi jẹ - ìyá ọmọ àkanda
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

World Autism Day: Ojojúmọ ní mọ ń kẹ́kọ̀ọ́ lára ọmọ mi to jẹ akanda

Gẹ́gẹ́ bi ọjọ òní ṣe jẹ ọjọ àwọn àkanda ọmọ lágbàyé, Ilaniloye tí ń tàn kálẹ̀ láti ríi dáju pe kò si ìdẹ́yẹ si gbogbo àwọn to ba jẹ àkanda ní àwùjọ wa.

Ajọ ìsọkan àgbáyé ní ó ṣe pàtàki láti ràn wọn lọ́wọ́ ki wọn si jẹ ki wọn maa kópa ninu nkan awujọ ki wọn le ṣe àṣeyori nínú òhun ti wọn ba dáwọlé.

BBC Yorùbá bá òbí ọmọ àkanda kan sọ́rọ̀ lóri ìpàníja tí ń koju lóri ọmọ náà.

Obìnrin òun ti kò fẹ ki a dá orukó òun sàlàye pé ó ṣe patakì láti máa dúpẹ nínú ohun gbogbo nítori pe àwọn ọmọ náà jẹ ẹbun pàtaki, sùgbọ́n nítori pe oye rẹ bi wọn ṣe ri kò ti ye ọpọ ènìyàn láwujọ pàápàá ni Nàìjírìà.

O fi kún pe ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ àkanda yìí kìí ni òòre ọ̀fẹ́ láti joko ju ìṣẹ́ju mẹ́ẹ̀dógun lọ láti kẹ́kọ̀ọ́ tabi ṣe iṣẹ́, sùgbọ́n, wọn jẹ onímọ gidigidi ti ènìyàn ba fi ara balẹ̀ fun wọn.

O sàlaye pe òbi ni láti ma á farabalẹ̀ fun wọn gidigidi nítori ki àwọn náà le di èèyàn lẹ́yìn wá ọ́la,

"àwọn ọmọ náà máà ń ni ìfẹ ènìyàn, ojú ti wọn fi ń wo aye si yàtọ si ti àwọn ènìyàn tóku.

Related Topics