Ìgbìmọ̀ iṣedajọ orílè-èdè Nàìjíríà NJC nikan lo le yọ adajọ-Amofin

Aworan awọn adajọ agba

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Ilé igbimọ aṣofin n beere pe ki wọn yọ adajọ agba ipinlẹ Kogi

Awuyewuye to n waye nipinlẹ Kogi nipa yiyọ adajọ agba ipinlẹ naa ti mu ki awọn eeyan máa beere ibeere kan eleyi to niṣe pẹlu boya awọn ẹka ijọba miran lagbara lati yọ ọsiṣẹ ẹka iṣedajọ.

Ọrọ yi ko jẹ tuntun lagbo oṣelu Naijiria ṣugbọn igba kigba to ba gbori sita, niṣe ni iriwisi ọtọtọ a ma tele.

Lọjọ kini, oṣu kẹrin ni sẹnetọ to n ṣoju ila oorun ipinlẹ Kogi, Dino Melaye ke gbajare loju opo Twitter nipa ete ti awọn kan n pa lati yọ adajọ agba ipinlẹ naa nipo.

Ninu ọrọ rẹ, o fẹsun kan pe awọn kan ti pari ipade eyi ti wọn ti paṣẹ ki olori ile aṣofin ipinlẹ naa yọ adajọ agba nipo bi bẹ kọ wọn yoo yọ ohun gaan alara.

Asẹyinwa aṣẹyinbọ ọrọ yi ni ikede ile asofin eleyi ti wọn ti daba ki wọn yọ adajọ agba Nasir Ajana nipo lori ẹsun aṣemaṣe.

Ohun nikan kọ, abajade iwadii igbimọ ile to n ri si amojuto eto owo ara ilu sọ pe ki adajọ agba naa yẹba lati le dahun si ẹsun ti ayẹwewo agba ipinlẹ naa fi kan an.

O jọ gate ko jọ gate, ibi ti ọrọ naa yoo kangun si ko ti ye wa ṣugbọn BBC beere alaye lọwọ agbẹjọro kan lori iha ti ofin kọ si yiyọ adajọ agba

Ìgbìmọ̀ iṣedajọ orílè-èdè Nàìjíríà NJC nikan lo le yọ adaj

Agbẹjọro Solihu Adebayo nilu Ibadan ṣalaye fun ile iṣẹ BBC Yoruba pe lootọ lawọn ẹka aṣofin le daba yiyọ adajọ agba ṣugbọn igbimọ iṣedajọ orile-ede Naijiria NJC nikan lo lagbara lati yọ ọ.

O ni ipinya laarin awọn ojuṣe ati agbara ẹka ijọba ko fayegba ki ẹka iṣejọba kan máa dasi iṣẹ ẹka miran bi ki ṣe nilana ohun ti iwe ofin ilẹ Naijiria sọ.

Oríṣun àwòrán, Facebook/Adebayo Solihu

Àkọlé àwòrán,

Agbẹjọro Solihu Adebayo ni aṣilo agbara ni ki awọn ẹka ijọba miran ma yọ adajọ nipo

''Ẹka ẹyọ kan ṣoṣo ti ofin sọ ti o si ni agbara lati yọ adajọ ni Naijiria ni NJC''

O salaye siwaju pe ''ko si ẹni ti ko le kọ iwe ẹsun nipa adajọ,koda ara ilu le kọ ti wọn ba fura si pe irin ẹsẹ adajọ ko mọ''

Nipa iroyin to n ja rain wi pe ijọba ipinlẹ Kogi fẹ lo awọn ọmọ ogun ati ọlọpaa lati yọ adajọ naa nipo,o ni eleyi tako ofin

''Ati ọlọpaa, ati awọn ọmọ ogun ti o ja si pe wọn wa labẹ ẹka alasẹ, ko si ẹni ti ofin gba laye ninu wọnlati yọwọ adajọ lawo bi kii ṣe wi pe aṣẹ na wa lati ọdọ ẹka idajọ fun arawọn'' .

Àkọlé fídíò,

Àyà mi kọ́kọ́ máa ń já nígbà ti mo ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ -Alaga iduro ọkùnrin

Njẹ ẹka idajọ Naijiria ni ominira ni tootọ?

Iṣẹlẹ ẹnu ọjọ mẹta yi nipa ibaṣepọ laarin ẹka alaṣẹ ni Naijiria ati ka idajọ n tọka si pe ohun gbogbo ko lọ deede laarin awọn mejeeji.

Bi a ko ba gbagbe, laipẹ yi ni awuyewuye waye lori bi aarẹ Naijiria ti ṣe paṣẹ lọ rọọkun nile fun adajọ agba orile-ede naa, Adajọ Walter Onnoghen.

O ye mi-ko ye ẹ lori ọrọ yi mu ki awọn kan máa sọ pe ẹka alaṣẹ n dunkooko mọ ẹka idajọ ti ọrọ naa si ti mu alaye orisirisi wa lodo awọn amofin.

Àkọlé àwòrán,

A ò ṣe àyọnusọ lóri ọ̀rọ̀ abẹ́lé Nàìjíríà-UK

Ọrọ yii mu ki awọn eeyan ṣi iwe kan iru igbeṣẹ bayi ti Gomina ipinlẹ Kwara nigba kan ri Bukola Saraki hu pẹlu yiyọ adajọ agba ipinlẹ naa Adajo Elelu Habeeb.

Ile ẹjọ giga dasi ọrọ naa ti o si sọ pe ofin ko fun Gomina tabi aarẹ orile-ede lagbara lati yọ adajọ kankan yala nipinlẹ tabi adajọ agba lorile-ede.

Bi ọrọ ti ṣe ri yi agbẹjọro Solihu Adebayo ni ''Ko ruju ni nnkan ti ofin sọ. Bi a ba kan fẹ tan ara wa loku, ko si agbara lọdọ ẹnikẹni yatọ si igbimọ iṣẹdajọ lati yọ adajọ''.

Àkọlé fídíò,

Okùnrin SARS náà sọ pé òun máa pa èèyàn síbi ni- Aladugbo

Àkọlé fídíò,

Ojojúmọ ní mọ ń kẹ́kọ̀ọ́ lára ọmọ mi to jẹ akanda