Ilé ẹjọ́ kòmítẹlọ́rùn yá lórí ìbò gómìnà Oṣun- PDP

Ilé ẹjọ́ kòmítẹlọ́rùn yá lórí ìbò gómìnà Oṣun- PDP

Ẹgbẹ oṣelu PDP ti sọ pe ohun yoo lọ si sile ẹjọ kotẹmilọrun lori idajọ ile ẹjọ giga l'Abuja to fagile iyansipo Ademola Adeleke gẹgẹ bi oludije sipo gomina fẹgbẹ oselu PDP ninu idibo gomina to waye ninú Osu Kẹsan, ọdun 2018 ni ipinlẹ Osun.

Lasiko to n da ẹjọ naa, Adajọ Agba Oathman Musa sọ wi pe iwadii fihan pe ọdun 1976 ni Adeleke wọ ile iwe girama, amọ ti ko si iwe ẹri to fihan pe o jade iwe mẹwa ni ọdun 1980.

Ṣugbọn oluranlọwọ fun Sẹnẹtọ Adeleke lori eto iroyin Bamidele Salami to ba BBC Yoruba sọrọ ṣalaye pe idajọ naa ko lẹsẹ nilẹ rara.