Fake Facebook: Ọkùnrin kan dèrò iléejọ́ lórí ẹ̀sùn pé ó f'orúkọ Adeboye lu jìbìtì

Daniel Olukoya, Enoch Adeboye ati Temitope Joshua Image copyright Twitter/Adeboye/Olukoya/Joshua
Àkọlé àwòrán Ọkunrin kan fawọn ojiṣẹ Ọlọrun lo jibiti

Ọwọ ti ba ọkunriun kan ti wọn fẹsun kan pe, o n fi orukọ Olori ijẹ Redeem, Enoch Adeboye, ati ti ijọ Mountain of Fire, Daniel Olukọya pẹlu Olori ijọ Synagogue, Temitọpẹ Joshua lo awọn eeyan ni jibiti.

Ọkunrin naa ti orukọ rẹ n jẹ Yusuf Atanda, ni wọn fẹsun kan pe o ṣi oju opo ayederu Facebook fun awọn ojiṣẹ Ọlọrun mẹtẹẹta yii lati maa fi gba owo lọwọ awọn eeyan.

Iwadii fihan pe, Ọgbẹni Atanda fi atẹjiṣẹ sọwọ si awọn eeyan lati maa fi owo bi ẹgbẹrun kan ati ẹgbẹrun un meji naira si akoto banki to fi ranṣẹ si wọn.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionAyekofẹnifọrọ: Ó yá, ẹ fi àmì sórí ọ̀rọ̀ náà.

Iroyin sọ pe, kete ti Ọgbẹni Atanda ba ti rowo gba lọwọ awọn eeyan ni yoo pa oju opo Facebook wọn rẹ, ki wọn ma ba le mọ ibi to wa.

Ẹwẹ, wọn gbe ọkunrin naa lọ siwaju ileejọ Magisireeti l'Ọjọru nibi to ti sọ pe oun ko jẹbi ẹsun naa.

Adajọ M.O. Tanimọla sun igbẹjọ naa siwaju si ọjọ kẹtadinlogun oṣu yii.