UI- Ìwádìí àyẹwò nìkan ló lè sọ ohùn tó pá olùkọ́ tó kù nínú ilé to jo

Aworan aaye ibusun Othman Zubair to ku Image copyright Tunji Oladejo
Àkọlé àwòrán Ori ibusun ti awọn panapana ti gbe ọgbẹni Othman Zubair lọ si ile iwosan

Ile Ẹkọ fasiti ilu Ibadan,ti ọpọ mọ si UI ti fesi si iku arakunrin kan to ku mọ inu filati kan to jona laaye ibugbe awọn oṣiṣẹ agba ile Ẹkọ naa .

Ọgbẹni Aminu Othman Zubair ni iroyin kan so pe o gbẹmi ara rẹ ninu iṣẹlẹ ti ina ti jo filati rẹ nikan.

Amọ,alukoro ile Ẹkọ fasiti naa ọgbẹni Tunji Oladejo ninu ifọrọwanilẹnuwo pẹlu BBC salaye pe awọn ko ti le sọ pato nnkan to ṣokunfa iku arakunrin naa.

Oladejo ni lootọ ni aaye ibugbe Zubair jona ṣugbọn nigba ti awọn panapana yoo fi pa ina na ko si apẹrẹ pe ina jo Othman Zubair mọ ori ibusun rẹ ti wọn ti ba.

Image copyright Tunji Oladejo
Àkọlé àwòrán Awọn yara kan jo ninu ile Othman Zubair ki awọn panapana to ribi pa wọn

''Ori ibusun ti o sun si, ina yẹn ko de ibẹ,amọ gbogbo ibi iyoku ninu ile naa lo jo.Nigba ti wọn yoo fi gbe de ile iwosan Jaja, o ti ku''

O tẹsiwaju pe awọn alayẹwo ko ti gbe esi iwadi ohun to sọkunfa iku rẹ,fun idi eyi awọn ko le sọ iru iku to pa.

Image copyright Tunji Oladejo
Àkọlé àwòrán Ori lo yọ awọn olugbe ile to ku lọwọ ewu ina naa

BBC Yoruba wadi lọwọ alukoro fasiti naa boya oloogbe ohun ni ipenija ti o le mu gba ẹmi ara rẹ ti o si dahun pe ohun kan mọ pe arakunrin naa ati iyawo rẹ ni ede aiyede eleyi ti o mu ki wọn pinya.

''Nigba ti iṣẹlẹ yi yoo fi ṣẹlẹ kii ṣe oṣiṣẹ wa mọ, fun ara rẹ lo kowe pe oun ko ṣiṣẹ mọ ṣugbọn a kan fun laaye ko ma gbe ibẹ ni tori pe oju lo n roju ṣaanu''

Ogbẹni Tunji Oladejo fidi ọrọ mulẹ pe awọn mọlẹbi oloogbe naa ti sin oku rẹ si iboji oku to wa ni Akinyele.