Ààrẹ Buhari- Boko haram kò f'ẹsẹ rinlẹ l'ágbègbè kánkan ní Nàìjíríà

Muhammadu Buhari Image copyright @NGRPresident

Bi o ba jẹ ti ọrọ ikọ Boko Haram ni, wọn ko ni agbegbe Naijiria kankan ti wọn dimu.

Aarẹ orile-ede Naijiria, Muhammadu Buhari lọ sọ ọrọ yi di mimọ nibi ipade apero eto ọrọ aje l'agbaye ni ẹkun Middle East ati North Africa to n waye ni Amman lorileede Jordan.

O ni awọn ọmọ ogun orileede Naijiria ti gba gbogbo agbegbe ti Boko Haram gba lọdun 2014 pada lọwọ wọn.

O ṣafikun pe ijọba ohun ti doola ẹmi awọn ti Boko Harm ko ni panpẹ mọra.

Ọrọ rẹ yi n waye lasiko ti ipenija aabo ti ṣe n koju awọn ipinlẹ kọọkan lariwa Naijiria bi Zamfara ati Kaduna.

Bo tilẹ jẹ wi pe Boko Haram ko lagbara to titẹlẹ mọ, ko ti si aridaju wi pe ijọba ti ribi yọ ọwọ wọn lawo patapata.

Aarẹ Buhari ninu ọrọ rẹ tubọ salaye pe aisi anfaani eto igbayegbadun ati aikari mudunmudun eto ọrọ aje lo mu ki ipenija aabo ma peleke si lagbaye .

O ni lorile-ede Naijiria, ijọba sapa lati mu irọrun ba awọn eeyan pẹlu ipese awọn eto kan eleyi to mu ki Naijiria ṣi sii fun karakata pẹlu awọn orile-ede miran.