Aliko Dangote: Mo gbà $10m ní bánkì kí o lè dami loju pé lòótọ́ ní mò lowo

Dangote Image copyright BBC/GETTY

Olokoowo to lowo ju lọ ni Afrika Aliko Dangote ti ṣọ bi ohun ti ṣe gba miliọnu dọla mẹwa ni banki tori pe ohun fẹ mọ daju pe lootọ ni ohun lowo to to bẹ.

Nibi apero Mo Ibrahim to waye ni ọjọ abamẹta nilu Abidjan, ni o ti sọrọ yi.

Aliko Dangote to ni ile iṣẹ orisiriṣi sọ pe ''nigba ewe,miliọnu akọkọ to ba ni yoo ma jọ ọ loju. Amọ lẹyin igba naa, ko ni jọju mọ.''

O salaye pe ohun ṣadede lọ ile ifowopamọ lati lọ gba miliọnu mẹwa dọla ti oun si gbe si ẹyin ọkọ.

O ni ''nigba ti mo de ile,mo wo owo naa niwo pe lootọ ni pe emi ni mo ni.''

Image copyright Getty Images

Nigba ti o di Ọjọ Keji, Dangote ni ohun da owo naa pada si banki.

Ki a yabara kuro nidi ọrọ yi lati gbọ nnkan mi to sọ nibi apero naa.

Iṣẹ agbẹ ati imọ ẹrọ lafojusun ọjọ iwaju

Dangote parọwa si awọn ọdọ Afrika lati ma ṣe jẹ ki ọrọ wọn dabiowe Yoruba to niowo ti ọmọde ba kọkọ ri,akara nii fi jẹ

O ni ki wọn ni adisọkan to rinlẹ ki wọn si ma na inakuna

Image copyright ERIC PIERMONT
Àkọlé àwòrán Pupọ ninu owo Dangote wa lati idi ọja Dangote Cement rẹ

''Lọpọ igba, ati oju owo ati ere,gbogbo rẹ ni a ma n na.Ẹ ma gbagbe pe a ko ni ma ṣalai koju ipenija ninu idokowo''

O mu apere ipenija ti ohun koju pẹlu ile iṣẹ simẹnti rẹ plu bi orileede Benin to wa ni tosi Naijiria ti ṣe yan rira simẹnti lati orileede China dipo tirẹ to wa ni arọwọtoo wọn.

Dangote kasẹ ọrọ rẹ pẹlu pe ohunn banujẹ nipa wahala gbigbe nkan gba ibode kan si omiran nilẹ Afrika.

Related Topics