#Zamfarakillings: Ìjọba pàṣẹ kí wọn dáwọ́ ìwakùsà ní Zamfara

Buhari Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ọjọ́ Etí ni Abẹnugan Ilé Ìgbìmọ̀ Aṣòfin ìpìnlẹ̀ Zamfara fi léde àwọn jàgúdà tí pa ènìyàn 50 tó jẹ́ ọmọ ẹgbẹ JTF.

Ijọba apapọ lorilẹ-ede Naijiria ti pasẹ ki wọn dawọ duro lori gbogbo iṣẹ iwakusa lagbegbe ilu Zamfara lẹsẹkẹsẹ.

Igbesẹ yii ko sẹyin bi awọn jaguda kan se pa aadọta eniyan ni agbegbe naa lopin ọsẹ.

Ọga Agba Ajọ Ọlọpaa lorilẹ-ede Naijiria, Mohammed Adamu to fi ọrọ naa lede lasiko to n ba awọn oniroyin sọrọ ni ilu Abuja sọ wi pe awọn gbe igbesẹ naa lati ri wi pe abo to gbooro wa lori awọn osisẹ lagbegbe naa.

Adamu wa kesi awon ajeji to wa lati ilu okeere lati wa sisẹ ni bẹ lati kuro ni bẹ ni wara n ṣesa, ki ijọba ma ba a gba iwe asẹ ati ṣe iwakusa lagbegbe naa.

Ààrẹ Buhari bínú sí àwọn afẹ̀họ́nú hàn

Aarẹ orilẹ-ede Naijiria, Muhammadu Buhari ti sọ òkò ọrọ si awọn afẹhọnu han ti wọn ni ko kọ ibi ara si ipaniyan to n waye ni ilu Zamfara.

Ninu atẹjade lori oju opo Twitter rẹ, Buhari sọ pe oun ba awọn ara ati ẹbi awọn eniyan ti jaguda pa ni Ọjọ Ẹti kẹdun.

O ni ohun ibanujẹ lo jẹ fun oun wi pe awọn adigunjale gba ẹmi awọn eniyan aadọta to jẹ ọlọde, JTF.

Aarẹ Muhammadu Buhari wa fi kun wi pe ohun to pọn dandan fun oun lọwọlọwọ bayii ni lati fi opin si iwa ipaniyan lagbegbe Ariwa orilẹ-ede Naijiria.

Laipẹ yii ni awọn eniyan bẹrẹ si ni fẹhọnu han lori awọn eniyan ti wọn n ṣekupa nipa wiwọ aṣọ pupa lati fi ibanujẹ wọn han.

Aarẹ orilẹ-ede Naijiria naa wa rọ awọn ọmọ orilẹ-ede Naijiria lati ma ṣe ti ọrọ oselu bọ ipaniyan to n waye naa, ki awọn ba le tete ri awọn to n ṣiṣẹ ibi yii, ki wọn si fi wọn jofin.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionOjojúmọ ní mọ ń kẹ́kọ̀ọ́ lára ọmọ mi to jẹ akanda
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionÀyà mi kọ́kọ́ máa ń já nígbà ti mo ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ -Alaga iduro ọkùnrin