UNILAG Child Molestation: Ọ̀jọ̀gbọ́n Fagbohungbe ní àwọn òbí ayé òde òní kò ṣiṣẹ wọn bí iṣẹ́

Ọmọdebinrin Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán ohun buruku ni agba fipa ba ọmọde lo pọ tabi tami oge sii lara

Ọjọgbọn Fagbohungbe Bankole Oni sọ pe awọn obi aye ode oni ko ṣiṣẹ wọn bii iṣẹ mọ.

O woye pe eleyi lo n ṣe okunfa ki awọn ara ita maa fipa ba awọn ọmọ kekeeke tage tabi ni ibalopọ pẹlu ipá.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionKọ́ ọmọ rẹ lẹ́kọ̀ọ́ ìbálọ̀pọ̀- Ọ̀jọ̀gbọ́n Fagbohungbe

O sọrọ yii ninu ifọrọwerọ pẹlu BBC Yoruba nigba ti o n sọ iwoye rẹ lori akẹkọọ ọmọ ọdun mẹrin ti awakọ kan fipa ba tage nile iwe alakọbẹrẹ nipinlẹ Eko.

O gba awọn obi niyanju lati maa kọ awọn ọmọ wọn lẹkọ ibalopọ lati igba ti wọn be ti wa ni kekeke.

Ogbẹni Akinọla Akinrọpo, to jẹ olukọni nipa itọju ọmọ laijẹbi ṣalaye pataki ipa obi ati alagbatọ lasiko yii pe:

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionParental Guidance: Ọdún méjì ni kí ẹ ti bẹ̀rẹ̀ kíkọ́ ọmọ nípa ìbálòpọ̀
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionAyekofẹnifọrọ: Ó yá, ẹ fi àmì sórí ọ̀rọ̀ náà.

Olukọ ile iwe alakọbẹrẹ ti Women Society nile iwe giga fasiti UNILAG niluu Eko, Charity Madumere ni wọn ti da duro bayii pé ko lọ rọọkun nile na lori ẹsun pe awakọ ile iwe naa, Abiodun Matthew ba akẹkọọ ọmọ mẹrin tage lọna aitọ.

Igbimọ alaṣẹ ile iwe naa sọ pe iwadii fihan wi pe olukọ naa maa n fi awọn akẹkọọ ṣọ Ọgbẹni Matthew nitori ibaṣepọ to wa laarin awọn mejeeji.

Iwadii fihan pe nigba ti olukọ Madumere fawọn ọmọ kekeke ṣọ awakọ yii gan an lo fipa ba ọmọ ọdun mẹrin yii tage lọna aitọ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionOjojúmọ ní mọ ń kẹ́kọ̀ọ́ lára ọmọ mi to jẹ akanda

Baba ọmọ ti iṣẹlẹ yii sẹlẹ si, Ọgbẹni Ade ṣalaye pe oun ṣakiyesi pe ibaṣepọ to wa laarin olukọ ti wọn da duro ati awakọ yii mu ifura dani.

Ṣugbọn Ọgbẹni Ade sọ pe iṣẹlẹ naa ṣẹlẹ si ọmọ oun nitori wọn kẹ eti ikun si ikilọ ohun.

Lẹyin naa ni awọn ọlọpaa mu olukọ yii, igbakeji rẹ ati almojuto ti wọn si juwọn si atimọle.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionAyekofẹnifọrọ: Ó yá, ẹ fi àmì sórí ọ̀rọ̀ náà.
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionÀyà mi kọ́kọ́ máa ń já nígbà ti mo ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ -Alaga iduro ọkùnrin