Lagos Kidnap: Wo ohun tí ọlọ́pàá ti ṣe nípa àwọn méje tí wọ́n jí gbé l'Eko

Awọn ọlọpaa Naijiria Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Awọn ọlọpaa Naijiria

Ile iṣẹ Ọlọpaa ipinlẹ Eko ti sọrọ lori ibi ti wọn ba iṣẹ de lori ọrọ adari kan nile iṣẹ pana-pana, Rashidi Musbau atawọn mẹfa mii ti wọn ji gbe.

Ariwo ipaniyan, ijinigbe nihin lọhun atawọn wahala to n da silẹ n kọ ni lominu lorilẹede Naijiria.

BBC ba alukoro ile iṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko, DSP Bala Elkanah sọrọ.

Elkanah jẹ ko di mimọ pe oju ọna omi Ikorodu ni awọn afurasi janduku gba yọ si wọn ti wọn da wọn lọna.

Wọn ji adari ẹka nile iṣẹ pana pana ipinlẹ Eko, Rashidi Musibau atawọn mẹfa mii ti wọn jọ n lọ gbe ni ọjọ abamẹta to kọja wọn si gbe wọn lọ si ibi ti wọn ko mọ.

O ni "kọmisọna ọlọpaa ti ṣe ibẹwo sibẹ, nibi ti wọn ti ri awọn ọkọ pẹlu awọn ohun kọọkan to le wulo fun wa fun iroyin".

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionAyekofẹnifọrọ: Ó yá, ẹ fi àmì sórí ọ̀rọ̀ náà.

Ẹ̀ka alafọgbọn wadii ti ile iṣẹ ọlọpaa Eko ti wa lẹnu iṣẹẹ ṣiṣe awari awọn ti wọn ji gbe atawọn ajinigbe ọhun, yoo si di ṣiṣe lai fi ohunkohun silẹ lai ṣe.

Alukoro ọlọpaa ni ẹbi awọn ti wọn ji gbe kankan ko tii kan si ile iṣẹ ọlọpaa lati fun wọn ni iroyin kankan ṣugbọn awọn n ṣe iṣẹ awọn lọwọ lọwọ.

Gẹgẹ bi iṣẹlẹ ipaniyan ijinigbe ṣe n waye lọtun losi lorilẹede Naijiria eyi ti ariwo rẹ kọkọ pọ ni iha ariwa to fi wa di pe o tun sun de ipinlẹ Eko naa bayii ti ibẹru bojo si bo awọn eniyan lati rinrin ajo, Elkanah fesi.

O ni ọkan iru ẹ ni eleyii lati ọdun pipẹ, awọn si n ṣe iṣẹ awọn lati boju wo ohun to ṣi alafo silẹ ati ọna ati di alafo naa pẹlu.