Imo Airport Fire Outbreak: Iná sọ ní pápákọ̀ òfurufú ìpínlẹ̀ Imo

Papakọ ofurufu ipinlẹ Imo Image copyright DANIEL NWACHUKWU
Àkọlé àwòrán Papakọ ofurufu ipinlẹ Imo

Lẹyin ti ijamba ina kọ lu papakọ ofurufu ipinlẹ Imo, igbokegbodo irinajo ti gberasọ pada.

Ni ọjọ aje, ọjọ kẹjọ oṣu kẹrin ni iṣẹlẹ ijamba iná yii waye ní pápákọ̀ òfurufú ìpínlẹ̀ Imo.

Akọroyin BBC fi aridaju han pe ina naa pọ jọjọ to bẹẹ ti wọn dari irinajo pẹlu baalu lọ si ilu Portharcourt.

Image copyright DANIEL NWACHUKWU
Àkọlé àwòrán Papakọ ofurufu Imo

Ipaya bẹ silẹ gẹgẹ bi ina naa ṣe bẹrẹ si ni jo wii wii ni ẹnu ọna abawọle papak ofurufu Sam Mbakwe ni ilu Owerri, ipinlẹ Imo.

Ohun to ṣokunfa ina naa ko tii hande gẹgẹ bi a ko tii gbọ latẹnu awọn alaṣẹ tọrọ kan gan.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media caption'Celestine fa adá yọ, ó sì gé orí ọmọ mi méjì'