Ido-Ani Robbery: Àwọn adigunjalè pa ènìyàn mẹ́fà ní báńkì kan nìpínlẹ̀ Ondo

Ẹnu ọna ileefowopamọ First Bank, Ido-Ani Image copyright Thenationonline
Àkọlé àwòrán Wọn fi agidi mu awọn oṣiṣẹ ileefowopamọ lati ṣi ilẹkun rẹ, ṣugbọn owo ti wọn ba nibẹ ko jọ wọn loju rara.

Iroyin to tẹ wa lọwọ ni pe awọn adigunjale ya wọ ile ifowopamọ kan ni ipinlẹ Ondo ni ọsan ọjọ Aje.

Gẹgẹ bi alukoro fun ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Ondo, Femi Joseph ṣe sọ fun BBC Yoruba, awọn adigunjale naa ya bo ile ifowopamọ First Bank to wa ninu ilu Ido-Ani nijọba ibilẹ Ọ̀sẹ́ , ti wọn si gbiyanju lati ko owo lọ.

Ileefowopamọ ọhun nikan lo wa ni ilu Iso-Ani.

Ọwọ ọlọpa tẹ adigunjale ajọkọgbe nipinlẹ Ọsun

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionOffa Robbery: Àwọn aráàlú ṣi n gbé nínú ìpaya lẹ́yìn ọdún kan

Ṣugbọn gbogbo igbiyanju wọn lati ri owo ko jade nibi ti ileefowopamọ naa n ko owo si lo ja si ofo.

Ibi kan ṣoṣo ti wọn ti ri owo gbe lọ ni ibi ẹrọ igbalode to n pọ owo jade.

Wọn fi agidi mu awọn oṣiṣẹ ileefowopamọ lati ṣi ilẹkun rẹ, ṣugbọn owo ti wọn ba nibẹ ko jọ wọn loju rara.

Eyi lo si fa a ti wọn fi yinbọn pa awọn ti wọn pa.

Ibinu pe wọn ko ri nkankan mu ninu ileefowopamọ naa ni wọn fi pa oṣiṣẹ banki mẹẹrin, to fi mọ ọga agba ileewe girama kan to wa gba owo, ati ọlọpaa kan.''

Ṣé Fulani daran-daran ni àwọn tó n jí ènìyàn gbé ní ìpínlẹ̀ Ondo?

Àfojúsùn àtúntò FSARS ni láti mú àgbéga bá iṣẹ́ ọlọ́pàá- IG

Ọgbẹni Joseph ṣalaye Aado abugbamu ti wọn n pe ni 'Dynamite' ni wọn fi fọ ilẹkun wọle sinu ileefowopamọ ọhun.

Amọ ṣaa, ọwọ pada tẹ ọkan lara awọn adigunjale naa nibi ti iṣẹlẹ naa ti waye.

"Ẹni ti ọwọ tẹ yii lo kọkọ gbe ọkọ ayọkẹlẹ rẹ wọ inu ileefowopamọ wa nibi iṣẹju maarun ṣaaju ki iṣẹlẹ naa to o waye lati fi imu finlẹ lori bi ayika ṣe ri.''

Nibayii, ileeṣẹ ọlọpaa ti n fi ọrọ wa ẹni ti ọwọ tẹ lẹnu wo ninu iṣẹ iwadii wọn.