Oronpotoniyun: Ẹ ka ìtàn ayé Aláàfin obìnrin àkọ́kọ́ tíí ṣe jagun-jagun orí ẹṣin tó mú ọmú kúrò láti jọba

Aláàfin Ọ̀rọ̀ǹpọ̀tọ̀niyùn

Oríṣun àwòrán, Yoruba Museum

Yoruba maa n sọ pe a ko ri iru eyi ri, a fi n dẹru ba ọlọrọ ni, nitori ko si ohun ti ko sẹlẹ ri nitori ko si ohun tuntun kankan labẹ ọrun.

Fun ọpọ eeyan, awọn obinrin kii jọba nilẹ Yoruba, yatọ si awọn ti wọn fi jẹa dle, ti yoo wa nipo oriade naa fun igba diẹ.

Koda, ọpọ lo gba pe obinrin ko le de ipo awọn ọba kan bii ti Alaafin tilu Oyo ati Ooni tilu Ile Ife.

Àwọn ìtàn mánigbàgbé tí ẹ le è ní ìfẹ̀ sí:

Amọ gẹgẹ ba a ti ka ninu itan nipa awọn nkan to ti sẹlẹ siwaju laye atijọ, awọn obinrin kan ti jẹ Alaafin ati Ooni ri, ti ko si gbọdọ jẹ ajeji si wa mọ lode oni.

Gẹgẹ ba ti ka itan rẹ lori itakun agbaye ati oju opo Wikipedia, Alaafin akọkọ to jẹ obinrin nilu Oyo ni Aláàfin Ọ̀rọ̀ǹpọ̀tọ̀niyùn.

Itan naa ni bi ko ba si ẹsẹ, ẹsẹ kii deede sẹ, bẹẹ si ni bi ko ba ni idi, obinrin kii jẹ Kumolu.

Aisi ọkunrin mọ to wa lati idile to n jẹ Alaafin lo fa sababi bi Aláàfin Ọ̀rọ̀ǹpọ̀tọ̀niyùn se di ọba lode Ọyọ.

Àkọlé fídíò,

50 Year old Ajayi Folashade: Mo ti kọ́kọ́ dán an wò ní 80s àmọ́, ó kàn ṣáà ń wù mi náà ni

Ta ni Oronpotoniyun, obinrin akọkọ to jẹ Alaafin Oyo?

Apeja orukọ Alaafin obinrin akọkọ nilu Oyo ni Aláàfin Àjíún Ọ̀rọ̀ǹpọ̀tọ̀niyùn, to si maa n ki ara rẹ ni 'Ajiun, a rí òbò sẹgun ọ̀tẹ̀'.

Aláàfin Ọ̀rọ̀ǹpọ̀tọ̀niyùn jẹ Alaafin ilu Oyo laarin ọdun 1554 si 1562, nigba ti ko si ọkunrin mọ ni idile ọba to lee jẹ Alaafin.

Orukọ baba Aláàfin Ọ̀rọ̀ǹpọ̀tọ̀niyùn ni Alaafin Onigbogi, to n gbe ni ilẹ Ibariba, o tẹri gbasọ, ti arole rẹ, Alaafin Ofinran si jọba lẹyin rẹ.

Nigba ti Alaafin ofinran wa lori itẹ, ni wọn pinnu lati kuro ni ilẹ Ibariba lọ si Ọyọ, to si ko awọn eeyan rẹ ati awọn aburo rẹ lọwọ.

Orukọ awọn aburo rẹ naa ni Ọmọọba Eguguoju, Ọmọọbabinrin Ọ̀rọ̀ǹpọ̀tọ̀niyùn ati Ọmọọba Ajiboyede.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ki lo de ti Aláàfin obinrin, Ọ̀rọ̀ǹpọ̀tọ̀niyùn, se di Alaafin nilu Oyo?

Loju ọna ni ọkan lara olori Alaafin ofinran to loyun ti bi ọmọkunrin kan ti wọn pe orukọ rẹ ni Ọmọọba Tella Abiipa.

Loju ọna ni Alaafin Ofinran ti waja, ti Alaafin Oguguoju si gori itẹ lẹyin rẹ, oun lo si lewaju awọn eeyan rẹ de ilu Ọyọ Igboho.

Oyo Igboho yii si ni wọn tẹdo si lẹyin irinajo ọlọjọ gbọọrọ, ibẹ naa si Alaafin Oguguoju naa ku si pẹlu.

Ọkunrin to kan to yẹ ko jọba ni Ọmọọba Ajiboyede, amọ ọmọde patapata ni, ti ọkunrin miran to tun wa nilẹ, Ọmọọba Tella Abiipa, si wa lọmọ irakoro.

Ko wa tun si agbalagba ọkunrin miran ni idile Alaafin to lee gun ori itẹ mọ́ afi obinrin nikan soso.

Idi ree ti awọn Ọyọmesi, to jẹ Afọbajẹ, fi pinnu lati mase mu ọmọ oye laarin ara wọn.

Àkọlé fídíò,

Abiodun Duro Ladiipo, Moremi: Ǹ kò pé '40' ti Bàbá fi papòdà ṣùgbọ́n mo kọ̀ láti 'remarry'

Oyomesi ati Oronpotoniyun gbena woju ara wọn lori ẹni ti yoo jẹ Alaafin:

Amọ obinrin kan soso to dagba ni idile ọba, Ọ̀rọ̀ǹpọ̀tọ̀niyùn fi aake kọri, to si ni oun ni oun yoo gun ori itẹ Alaafin

Awọn Ọyọmesi naa taku pe eewọ, ko si ninu itan ri pe obinrin jẹ Alaafin, ti wọn si sọ fun Ọ̀rọ̀ǹpọ̀tọ̀niyùn pe ko seese, afi ko jẹ ọkunrin ni yoo jẹ Alaafin

Ọ̀rọ̀ǹpọ̀tọ̀niyùn wa seleri fun wọn pe oun yoo fi han wọn pe ọkunrin ni oun, oun kii se obinrin, ati idi ti oun fi lẹtọ lati jẹ ọba.

O ni ki wọn pade oun ni ipebi ni ọjọ keje lati wa ri iran naa wo, to si bẹrẹ si ni wọ Agbada, buba ati sokoto bii ọkunrin lati igba naa lọ.

Oronpotoniyun mu ọmu kuro laya rẹ, fi nnkan ọkunrin rọpo ti obinrin to wa ni abẹ rẹ:

Ni ọjọ keje, ẹnu ya awọn Ọyọmesi ni Ipebi, nigba ti Ọ̀rọ̀ǹpọ̀tọ̀niyùn bọ ara rẹ silẹ fun wọn, ti wọn si ri pe ko si ọmu ni aya rẹ.

Bakan naa, wọn ri pe dipo nkan ọmọbinrin, nkan ọkunrin lo wa ni abẹ rẹ. Idi si ree to fi n ki ara rẹ ni 'Ajiun, a rí òbò sẹgun ọtẹ'

Kiakia ni wọn dọbalẹ fun, ti wọn si n se ni Kabiesi. Lẹyin eyi lo jẹ Alaafin ti igba rẹ tuba, tusẹ, to si sẹ oniruuru ogun fun ilu Ọyọ.

Àkọlé fídíò,

Obateru Akinruntan: Wíwá ohun tá jẹ títí láé ló gbé wa kúrò nílé Ife

Oronpotoniyun ni ẹda akọkọ to yipada lati obinrin si ọkunrin, bo se n waye lode oni:

Aláàfin Ọ̀rọ̀ǹpọ̀tọ̀niyùn gbowọ ninu lilo ohun ijagun, o jẹ jagunjagun to da musemuse, oun si ni ọbabinrin to sẹgun ogun awọn ẹya Nupe to maa n da Ọyọ laamu laarin ọdun 1555.

Ni aye ode oni, ẹkọ nla gidi ni itan igbe aye Alaafin obinrin akọkọ yii yẹ ko kọ wa, eyi to fi han wa pe ko si ohun ti ọkunrin lee se, ti obinrin ko lee se.

Bakan naa lo fi ye wa pe isẹ́ abẹ́ ko sẹsẹ bẹrẹ, o ti wa lati atetekọse, ti awọn eeyan kan si gba pe Aláàfin Ọ̀rọ̀ǹpọ̀tọ̀niyùn ni ẹda akọkọ to jẹ obinrin, amọ to yipada si ọkunrin, gẹgẹ bawọn eeyan kan se n se lode oni.

O wa yẹ ko ye gbogbo wa bayii pe, ka ma se ilakaka pe a ko bi ọkunrin, tabi obinrin nikan la n bi jọ, nitori gbogbo lọmọ, ko si eyi ti ko wulo ninu wọn.

Àkọlé fídíò,

Female Carpenter: Fatia Garu ní ọ̀pọ̀ èèyàn ni kìí gbàgbọ́ pé obìnrin ló ń ṣiṣẹ́ Káfíńtà