INEC: Àwọn ẹgbẹ́ òṣèlú yóò dìbò àbẹ́lé lóṣù Kẹjọ

Awọ̀n eeyan to n dibo

Ajọ eleto idibo ilẹ wa ti kede pe ọjọ́ Kejì, oṣù Kọkànla, ọdún 2019 ni ìbò gómìnà nipinlẹ́ Kogi àti Bayelsa yóò wáyé.

Atẹjade kan ti ajọ INEC fi sita lọjọ Isẹgun, ti alaga ati kọmisọna to wa fun ẹka iroyin ati ilanilọyẹ oludibo, Festus Okoye fọwọsi, lo siṣọ loju iroyin yii.

Atẹjade naa ni ọjọ kinni, osu Kẹjọ, ọdun yii ni ajọ INEC yoo fi ikede nipa ibo naa to ipinlẹ mejeeji leti, nigba ti eto idibo abẹnu laarin awọn ẹlẹgbẹjẹgbẹ oloselu yoo maa waye laarin ọjọ Keji si ọjọ ikọkandinlọgbọn, osu Kẹjọ, ọdun 2019.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àkọlé fídíò,

Parental Guidance: Ọdún méjì ni kí ẹ ti bẹ̀rẹ̀ kíkọ́ ọmọ nípa ìbálòpọ̀

Iroyin naa ni Ọjọ Keji, osu Kẹjọ ni eto ipolongo ibo yoo bẹrẹ ni ipinlẹ mejeeji, ti yoo si wa sopin ni ọjọ Kọkanlelọgbọn, osu Kẹwa, ọdun 2019 naa.

Atẹjade ọhun wa n rọ awọn oludije labẹ ẹgbẹ oselu kọọkan lati fi orukọ awọn asoju wọn lọjọ idibo sọwọ, o pẹtan, ọjọ Keji, osu Kẹ́wa ọdun yii.

Àkọlé fídíò,

Ayekofẹnifọrọ: Ó yá, ẹ fi àmì sórí ọ̀rọ̀ náà.