JAMB 2019: JAMB ní ẹ̀rọ tó ń wo bó ṣe ń lọ ni ibùdó ìdánwò

JAMB 2019: JAMB ní ẹ̀rọ tó ń wo bó ṣe ń lọ ni ibùdó ìdánwò

Idanwo aṣewọ ile iwe giga JAMB ti gberasọ lonii, ọjọ kọkanla ti yoo si waye titi di ọjọ kẹtadinlogun, oṣu kẹrin ọdun 2019.

O le ni miliọnu 1.8 akẹkọọ to forukọ silẹ lọdun yii eleyii tumọ si pe o fi diẹ ju iye miliọnu 1.7 to forukọ silẹ lọdun to kọja, 2018.

BBC Yoruba ba ọga agba ile iṣẹ JAMB, Ọjọgbọn Ishiaq Oloyede sọ̀rọ̀ lori awọn ohun to n ru obi ati awọn oluṣedanwo loju lori idanwo JAMB ati gbigbani wọ ile iwe iwe giga lẹyin ti esi ba ti jade.

Oga agba ajọ yii gba pé ọpọlọpọ ile iwe giga ni awọn ti ko ba yege to ninu idanwo UTME ṣi le wọ bii ilẹ ẹkọ nipa iṣẹ itọju alaisan, ilẹ ẹkọ nipa ọsin ẹja ati bẹẹ bẹẹ lọ.

O ni o le ni ida ọgọta ninu ọgọrun un awọn akẹkọọ ti JAMB maa n fun ni ọna igbaniwọle kẹkọọ lọdọọdun.

Lónìí ọjọ́ kọkànlá, oṣù kẹrin sí ọjọ́ kẹtàdínlógún, oṣù kan náà ni ìdánwò àṣewọlé ìwé gíga UTME yóò wáyé jákè jádò Nàìjíríà.

Ojọgbọn Ishiaq ni bi awọn ile iwe giga kọọkan ṣe n sunkun ọ̀dá akẹkọọ ni awọn mii n ni akẹkọọ to n mu ile iwe awọn ti pọ ju, ṣe eyi wu mi ko wu ọ ni kii kuku jẹ ki ọmọ baba meji fẹ iyawo kan naa.

Bakan naa ni adari ajọ JAMB fun Naijiria ni ko si ikọlura ninu ọjọ idanwo UTME ati idanwo iwe mẹwaa lọdun 2019 rara.

O ni awọn adari ajọ idanwo mejeeji jọ joko papọ ki wọn to jọ kede ọjọ idanwo ni ki ọkan obi ati akẹkọọ le jọ papọ.

Lori ọrọ owo ajọ JAMB ti wọn fẹsun kan awọn kan pe wọn ṣe ni kumọkumọ, ni Ojogbọn Oloyede fi ara balẹ ṣalaye fun BBC Yoruba pe iṣẹ ti lọ jinna lori ẹ.

O ni ajọ naa ti da ẹni to ṣafiwe ọrọ pe ejo gbe owo JAMB to to miliọnu mẹrindinlogoji mi duro lẹnu iṣẹ.

O ni bakan naa ni wọn ti fa gbogbo awọn mọkanla ti ọrọ kan naa lọ sile ẹjọ gẹgé bi o ṣe yẹ labẹ ofin.

Adari JAMB ni ajọ ọhun ti n ri ninu owo ti wọn na ni inakuna naa gba pada diẹ diẹ nigba ti igbesẹ ṣi n lọ lori ọna ati ri awọn owo mii gba bi o ti yẹ labé ofin Naijiria.

Ni ipari, ọjọgbọn Oloyede ṣalaye nipa igbesẹ JAMB lati daabo bo awọn oṣiṣẹ wọn ki ẹnikẹni ma ro pe wọn le ṣe wọn lésẹ lasiko idanwo nitori pe ọmọ ijọba ni oṣiṣẹ JAMB.

Si idahun pé boya Oloyede a gba iṣẹ minista ti a ba fun un ninu iṣejọba aarẹ Buhari yii, O ni ọmọ ọdun marundinlaadọrin ti kuro lọmọde, isinmi lo ku ti ara n fẹ ati pe, ifọwọsowọpọ lo yẹ ki a ṣe fun minista to n tukọ eto ẹkọ Naijiria lọwọ nitori o n ṣiṣẹ daadaa.