Sudan: Omar al-Bashir, oníyàwó méjì tí kò bí'mọ kankan

Omar al-Bashir Image copyright ASHRAF SHAZLY
Àkọlé àwòrán Omar al-Bashir

Lẹyin ọgbọ̀n ọdun, orilẹede Sudan yoo ni adari tuntun latari bi awọn ologun orilẹede naa ṣe gba ijọba lọwọ Omar al-Bashir.

Awọn oniroyin ni yatọ si igbe aye rẹ gẹgẹ bii adari Sudan fun ọgbọn ọdun, awọn oun ti awọn eniyan mọ nipa idile rẹ ko pọ.

Ṣugbọn awọn oun ti ẹ lẹ má mọ̀ rèé:

1. Omar al-Bashir ko bimọ kankan

Omar al-Bashir ko ni ọmọ kankan. Iyawo meji ni o fẹ - Fatima Khalid ati Widada Babikar Omer. Ṣugbọn ko si ikankan lara wọn to bimọ fun.

2. Tani awọn iyawo mejeeji?

Ibatan rẹ ni iyawo akọkọ, Fatima. Widada bimọ fun ọkọ rẹ tẹlẹ to ku sinu ijamba ọkọ baalu kan ki Al-Bashir to fẹ.

3. Bawo ni ọrọ̀ Omar al-Bashir ṣe pọ to?

Iroyin fi han wi pe Al-Bashir wa lara olori orilẹede Afirika to lowo ju lọ. Luis Moreno-Ocampo, to jẹ olupẹjọ ile ẹjọ agbaye nigba kan ri sọ ni ọdun 2009 wipe Omar al-Bashir ko owo to to biliọnu mẹsan dọla (triliọnu mẹta aabọ naira) pamọ si awọn ile ifowopamọ to wa ni Ilẹ Gẹẹsi. Awọn iroyin miiran ni bii bilọnu kan dọla ni gbogbo ọrọ̀ Al-Bashir.

Image copyright AFP

Ki o to di pe awọn oloogun orilẹede Sudan yọ Al-Bashir nipo, ọpọlọpọ ọmọ orilẹede naa lo ti ku ninu ifẹhonuhan ti wọn ti n ke si i wi pe ko fi ipo silẹ lati oṣu kejila ọdun 2018.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Igbesẹ n lọ kikankikan lati rii pe aarẹ Omar al-Bashir kọwe fi ipo rẹ silẹ

Lẹyin ti awọn ologun yọ nipo ni Ọjọbọ, wọn gbe ijọba alaranṣe kalẹ kalẹ eyi ti yoo wa nipo fun ọdun meji.

Bakan naa ni wọn si tun kede eto ilu o fararọ ọlọdun mẹta lati moju to ohun gbogbo to yẹ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Awọn eeyan orilẹede Sudan ṣi n reti ohun ti ileeṣẹ iroyin ijsba orilẹede naa gbe jade lori ikede kan ti ileeṣẹ ọmọogun orilẹede ọhun n gbero lati ṣe lori bi eto iṣejọba orilẹede naa yoo ṣe ri.

Oniruuru iwọde lo ti n waye niorilẹede Sudan ninu eyi ti ọpọ araalu ti n pe fun igbejọbasilẹ aarẹ Omar al-Bashir.

Iroyin ti awọn eeyan orilẹede naa n wu gbọ bayii ni pe aarẹ al-Bashir ko ni pẹ gbe ijọba silẹ ṣugbọn ko tii si ikede kan ni pato lati ọdọ awọn alaṣẹ ilẹ naa.

Image copyright Getty Images

Bi o tilẹ jẹ pe ileeṣẹ akoroyinjọ Reuters ti gbee sita pe eeyan kan ti awọn fi oruks bo laṣiri ṣalaye fun awọn pe lootọ ni aarẹ Omar al-Bashir ti kọwe fi ipo silẹ gẹgẹ bii aarẹ orilẹede naa.

Ireti ọpọ ni pe ki wọn kede eyi lori ileeṣẹ iroyin ijọba orilẹede naa pẹlu bi iwọde ṣe n tẹsiwaju kikankikan fun ọjọ kẹfa laiduro bayii ninu eyi ti awọn eeyan ti n ke si aarẹ naa pe ko fi ipo silẹ.