Sudan coup: Ṣé ìfipágbàjọba àwọn ológun kò maa pọ̀ si l'Afirika?

Awọn ologun orilẹede Sudan Image copyright Getty Images

Lẹyin ọpọ ifẹhonu han, awọn ologun gbajọba lọwọ aarẹ orilẹede Sudan, Omar al-Bashir.

Ile iṣẹ ologun sọ pe ohun yoo ṣe amojuto bi eto idibo yoo ṣe waye laarin ọdun meji.

Aarẹ al-Bashir fun ra rẹ gori oye lẹyin ti awọn ologun fipa gba ijọba lọdun 1989, ko to di akoko yii ọpọ igba awọn ologun ti gbiyanuju lati fipa gbajọba lorilẹede Sudan.

BBC ṣe ayẹwo itan bi awọn ologun ṣe dasi iṣejọba lorilẹede Sudan ati kaakiri ilẹ Adalawọ.

Orilẹede Sudan ni iṣẹlẹ ifapajọba ti pọju ni gbogbo ilẹ adaluawọ, igba mẹẹdogun ni awọn ologun ti gbiyanju lati fipa gbajọba.

Ẹmẹrin ọtọọtọ ni wọn ri ijọba gba, ti awọn ologun ba ri ijọba Omar al-Bashir gba de lẹ, yoo di igba karun un ti ologun ri ijọba gba lorilẹede Sudan.

Ifipagbajọba nilẹ Afirika

Igba mẹfalelugba ni ifapagbajọba ti ṣẹlẹ nilẹ Afirika lati ọdun 1950, iwadii awọn onimọ eto oṣelu meji to jẹ ọmọ ilẹ Amẹrika, Jonathan Powell ati Clayton Thyne lo fidi ọrọ naa mu lẹ.

Itumọ ti wọn fun fif ipa gbajọba ni ọna ti ko tọ lati yọ olori ijọba kuro lori ipo.

Ṣugbọn ede-ai-yede saba maa n ṣẹlẹ lori itumọ ifipagbajọba, koda awọn ọga ologun ti koro oju si ifipagbajọba.

Fun apẹrẹ, ni Zimbabwe lọdun 2017 nigba ti awọn ologun gbajọba ọdun mẹtadinlogoji Robert Mugabe, ọgagun agba Sibusiso Moyo nigba naa sọrọ lori ẹrọ amuhunmaworan pe ko si ohun to jọ idtẹgbajọba.

Ọgbẹni Powell to jẹ onimọ nipa oṣelu sọ pe awọn ologun kii fẹ gbọ pe awọn fipa gbajọba.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Awọn ologun gbajọba ni Robert Mugabe

Powell ati Thyne ifipagbajọba to ba ju ọjọ meje lọ gan an ni a le pe ni ifipagbajọba.

Yatọ si eleyi to ṣẹlẹ ni Sudan, ifipagbajọba marun le lọgọrun lo ti kuna nilẹ Afirika nigba ti ọgọrun si ṣẹlẹ.

Orilẹede Burkina Faso lapa iwọ oorun Afirika ni ifipagbajọba ti ṣẹlẹ julọ, ẹmeeje ọtọọtọ ni ifipagbajọba ti ṣẹlẹ ni orilẹede naa.

Bawọ ni ifipagbajọba ti pọ to nilẹ Afirika?

Ifipagbajọba ti ṣẹlẹ lọpọ igba nilẹ Afirika, ṣugbọn ọna lati fipa gbajọba iru eleyi ko wọ pẹ mọ.

Military coups in Africa

Source: Research by Florida and Kentucky Universities

Laarin ogoji ọdun(1960-2000), ifipagbajọba ṣẹlẹ nigba ogoji laarin ọdun mẹwaa.

Ṣugbọn iṣẹlẹ yii ko dabi ti tẹlẹ mọ, lati ọdun 2000, igba mejilelogun lawọn ologun ti gbiyanju lati gbajọba.

Ṣugbọn igba mẹtadinlogun ni iṣẹlẹ ifipagbajọba ti ṣẹlẹ laarin ọdun mẹwaa sẹyin bayii.

Ifipagbajọba lagbaaye

Lagbaaye, ifipagbajọba ti ṣẹlẹ nigba 476 lati ọdun 1952.

Afirika ni iṣẹlẹ ifipagbajọba ti pọju lagbaaye.

Ilẹ South Amẹrika lo tun tẹ le Afirika, igba marun un le laadọrun ni ifipagbajọba ṣẹlẹ, igba ogoji si lo kẹsẹjari.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ifẹhonu han lorilẹede Venezuela

Ni bi ogun ọdun sẹyin, iṣẹlẹ ifipagbajọba ti dinku nilẹ South America. Lọdun 2002 nigba ti irufẹ iṣẹlẹ waye lorilẹede Venezuela nigba ti awọn ologun fẹ ditẹ gbajọba aarẹ Hugo Chavez ṣugbọn wọn kuna.