Àwọn ará àdúgbó Lekki rí orí àti ara ọkùnrin mẹ́ta ní àdúgbo wọn

Awọn ara adugbo n pe wo oku ati ori awọn mẹta naa Image copyright Minkail Adesoji/Twitter
Àkọlé àwòrán Ibeere ti gbogbo ara adugbo to lọ ibi iṣẹlẹ naa ni pe ta lo pa wọn.

Ibẹru-bojo mu awọn ara adugbo agbegbe Abraham Adesanya ni Ajah, nilu Eko bi wọn ṣe ji ni aarọ ọjọ Aiku ti wọn si ba awọn oku arakunrin mẹta kan ti wọn ti ge ori wọn silẹ.

Oun to jẹ kayefi ni bi wọn gbe ori awọn ọkunrin mẹta naa, ti wọn si náà duro ni ẹgbẹ awọn oku naa.

Ibeere ti gbogbo aye fi lẹnu ni wipe, ta lo pa awọn ọkunrin mẹta yii? Awọn ara adugbo kan ni awọn lero wipe ikọlu awọn ọmọ ẹlẹgbẹ okunkun lo fa iku awọn oloogbe naa.

Àwọn ìròyìn mìíràn tí ẹ lè nífẹ̀ẹ́ sí:

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionÌfipálówó: Bàbá ọmọ tí wọn gé lórí ní òun rán an láti l gbowó lẹ́nu ATM ni

Nigba ti akọroyin BBC Yoruba kan si agbenusọ ileeṣẹ ọlọpaa ni Ipinlẹ Eko, Bala Elkana, o sọ wipe iwadi n lọ lọwọ lori bi awọn ọkunrin mẹta naa ṣe ku.

Ko ti i si ẹni to mọ orukọ awọn oloogbe naa tabi ibi ti wọn ti wa. Elkana ni awọn oun ti iwadii yoo fi han ree.

Ṣe ni awọn ara adugbo naa n fi aworan awọn oku naa sori atagba Twitter ti gbogbo ero si n lọ pe wo awọn oku ati ori naa ki awọn ọlọpaa to gbee lọ.