Cardless Withdrawal: Èyí ni àwọn ìlànà tí o le fi gbowó ní ATM láì lo káàdì

Kaadi ATM Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Yatọ si 'Cardless Withdrawal, awọn ọrọ ti awọn ileefowopamọ tun maa n lo ni Cash-on-The-Go, Dial4Cash, Magic Cash, ati bẹẹbẹ lọ.

Laipẹ yii ni iroyin gbe iṣẹlẹ kan to waye niluu Ibadan nibi ti awọn araalu ti lu arakunrin kan ni adugbo Dugbẹ nitori pe wọn ri t'oun gba owo lẹnu ẹrọ 'ATM' lai lo kaadi.

Eyi jẹ iyalẹnu fun awọn eniyan wọnyii ti ko mọ pe iru eto bẹ ẹ ti wa, ti o si ṣeeṣe ki wọn l'ero pe onijibiti ni ọkunrin naa.

Koda, wọn ko lu u nikan, niṣe ni wọn tun fa a le ọlọpaa lọwọ gẹgẹ bi arufin.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionÀmì ohùn ṣe pàtàkí nínú èdè Yoruba púpọ̀

Ṣugbọn ṣa, eto imọ ẹrọ̀ gbigba owo l'ẹnu ATM lai lo kaadi ti wa ni orilẹ-ede Naijiria lati ọdun 2014.

Igba naa si ni awọn onibara ileefowopamọ kan ti n lo o. Amọ, o da bi ẹni pe ọpọ ọmọ Naijiria ni ko ti i gbọ tabi mọ nipa ilana tuntun yii.

Imọ ẹrọ tuntun naa wulo lasiko ti o ba gbagbe tabi ti o ko ba mu kaadi ATM rẹ dani, ti o si nilo owo pajawiri.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionJAMB 2019: A ó fagi lé ìdànwò ẹni tó bá ṣe aṣemáṣe

O le tẹle awọn ilana yii lati bẹrẹ si ni i lo ilana tuntun naa.

 • Lori 'App' ileefowopamọ to wa lori ẹrọ ibanisọrọ alagbeka rẹ, tẹ 'Cardless Withdrawal' lara awọn igbesẹ ti o ba gbe wa fun ọ.
 • Ranti lati tẹ ẹ boya ẹka ileefowopamọ rẹ lo ti fẹ gba owo tabi ileefowopamọ mii.
 • Dahun gbogbo ibeere ti oju-ewe naa ba gbe wa fun ọ.
 • Ki o si tẹ 'pin', iyẹn numba mẹẹrin ti oun lo fun 'App' naa.
 • Lẹyin gbogbo igbesẹ yii, ileefowopamọ rẹ yoo fi awọn numba kan ranṣẹ si ori ẹrọ ibanisọrọ alagbeka rẹ. Numba yii ni o lo nidi ẹrọ ATM.
 • Nidi ATM wayi, tẹ 'Enter' lara awọn bọtinni to wa lara ATM naa.
 • Ki o si mu 'Cardless Withdrawal' lara awọn igbesẹ ti o ba gbe wa fun ọ.
 • Tẹ awọn numba ti wọn ti kọkọ fi ranṣẹ si ọ.
 • Tẹ iye owo ti o fẹ ẹ gba ( Eyi ko gbọdọ yatọ si iye ti o ti kọ tẹlẹ nigba ti o bẹrẹ igbesẹ naa lori ẹrọ ibanisọrọ rẹ).
 • Tẹ 'Enter' lati tẹsiwaju.
 • Gba owo rẹ.

Oladejo Okediji àti ìgbé ayé ìtàn kíkọ rẹ̀

Ọ̀wọ́ngógó epo bẹntirò: NNPC ni 'ìròyìn ẹlẹ́jẹ̀' ni

Ọlọ́pàá gbé àwọn tó yìnbọn lu olólùfẹ́ ní Ajegunle

Kínni ife ẹ̀yẹ ti Tiger Woods gbà ní Augusta fi yàtọ́?

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionParental Guidance: Ọdún méjì ni kí ẹ ti bẹ̀rẹ̀ kíkọ́ ọmọ nípa ìbálòpọ̀

Lati gba owo ni ileefowopamọ ti kii ṣe tiẹ:

 • Nidi ATM wayi, tẹ 'Enter' lara awọn bọtinni to wa lara ATM naa
 • Mu 'PayCode' lara awọn igbesẹ ti o ba gbe wa fun ọ
 • Tẹ numba 'PayCode' ti wọ̀n ti kọkọ fi ranṣẹ sori ẹrọ ibanisọrọ rẹ
 • Tẹ iye ti o fẹ gba ( Eyi ko gbọdọ yatọ si iye ti o ti kọ tẹlẹ nigba ti o bẹrẹ igbesẹ naa lori ẹrọ ibanisọrọ rẹ)
 • Tẹ 'Enter' lati tẹsiwaju
 • Gba owo rẹ

Yatọ si pe o le bẹrẹ igbesẹ naa pẹlu 'App' lori ẹrọ ibanisọrọ rẹ, o tun le lo awọn aṣayan numba ti ileefowopamọ rẹ n lo lati fun ẹrọ ibanisọrọ (Fun apẹẹrẹ *111#).

Lẹyin naa, tẹle awọn igbesẹ ti o ba yẹ

Yatọ si 'Cardless Withdrawal, awọn ọrọ ti awọn ileefowopamọ tun maa n lo ni Cash-on-The-Go, Dial4Cash, Magic Cash, ati bẹẹbẹ lọ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionỌ̀dọ́kùnrin tó kọ́kọ́ ṣe ẹ̀rọ tó ń tu ìyẹ́ lára adìyẹ