Senegal Artist: Ojojúmọ́ ni mo ń gbé àwòrán bàbá tó pọnmọ sẹ́yìn sójú pópó

Ọkunrin to pọn ọmọ sẹyin Image copyright Marta Moreiras

Sugbọn ni orilẹede Senegal, ayaworan kan, Marta Moreiras, ti kede pe aworan oun ti n fa oju awọn baba si isẹ ọmọ pipọn.

Marta Moreiras salaye pe oun ya aworan awọn baba to gbe ọmọ pọn sẹyin, ti oun si n gbe si oju popo ki awọn ero to n lọ, ati eyi to n bọ lee maa peju wo.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Igbesẹ yii si lo n mu ki ọpọ ero maa ya wa sidi aworan naa, , papaa awọn obinrin ti wọn si n kan saara si Marta Moreiras pe o seun.

"Awọn eeyan n patẹwọ fun mi, tawọn obinrin yoo maa ni ki n bọ awọn lọwọ, ọpọ ni yoo pe ọkọ rẹ lori aago, tori kii se ojoojumọ ni wọn n ri iru aworan bayii, bi o tilẹ jẹ pe o nira lati ya irufẹ aworan yii."

Image copyright Marta Moreiras

Gẹgẹ bi Marta Moreiras ti wi, ọdun 2008 ni ero yii wa si oun lọkan lasiko ti oun n wo ọkan ninu awọn aworan to wa ninu ile oun, to si ya aworan naa, ti wọn ti ya sọtọ fun ami ẹyẹ ayaworan to dantọ ti ileesẹ Sony fẹ se.

Image copyright Marta Moreiras

"Ẹnu maa n ya mi lati ri ọpọ aworan awọn iya to pọn ọmọ sẹyin amọ ti ko si aworan kankan nipa awọn baba to pọn ọmọ sẹyin. Nigba ti mo si bẹrẹ si pe awọn ọrẹ mi ọkunrin lati wadi idi ti eyi fi ri bẹẹ, wọn ni awọn lee pọn ọmọ sẹyin ninu ile sugbọn awọn ko lee se bẹẹ ni ita gbangba.

Image copyright Marta Moreiras

Iyapa nla lo n waye laarin inu ile ati ita yii, nitori eyi ni nkan se pẹlu oju ti awọn eeyan fi n wo wọn bi o tilẹ jẹ pe iwadi mi fihan pe isẹ nla lawọn baba n se ninu ile nidi itọju ọmọ.Nilẹ adulawọ, eewọ ni ki ọkunrin gbe ọmọ pọn sẹyin, nitori isẹ awọn obinrin ni ọmọ pipọn jẹ.

Image copyright Marta Moreiras