Ìtàn Mánigbàgbé: Duro Ladipọ fi òjò àti àrá ńlá sàmì ìpapòdà rẹ̀

Duro Ladipọ Image copyright Yomi Duro Ogunmola

Ni awujọ awọn osere tiata, odun ni oloogbe Duro Ladipọ, kii si se aimọ fun oloko. Bi onirese Duro Ladipọ ko si fingba mọ, eyi to ti fin silẹ ko to jade laye ko lee parun, tori pe o dabira lagbo tiata ko to jade laye.

Se bo se gbe isẹ tiata lọ soke okun ni ka sọ ni abi aimọye ere itage akọnilọgbọn to ti gbe se nigba to wa loke eepẹ.

Bi o tilẹ jẹ pe Duro Ladipọ ko si laye mọ, ọpọ awọn agba iwoyi ni ko lee gbagbe ere Ọba Koso, Sango, Ajagun Nla, Ẹda, Bode Wasinmi, ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Gẹgẹ ba se ka lori itakun agbaye Wikipedia, itan manigbagbe gbaa ni itan igbe aye oloogbe Duro Ladipọ, eyi to yẹ kawọn ode iwoyi fi se awokọse ati arikọgbọn gidi.

Ohun to yẹ ko mọ nipa Duro Ladipọ:

 • Ọjọ Kejidinlogun osu Kejila ọdun 1931 ni Duro Ladipọ de ile aye, ti wọn si bi si ilu Osogbo, se odo kii san, ko ma ni orirun
 • Ọmọlẹyin Kristi gidi, to wa lati idile onigbagbọ ni Duro Ladipọ, ti baba rẹ si jẹ ojisẹ Ọlọrun lati inu ijọ Angilika amọ baba baba rẹ to wa lati ilu Ọyọ ijọun, jẹ Onisango ati Ọlọya
 • Niwọn igba to jẹ pe ẹjẹ ni agbara, bi o tilẹ jẹ pe inu ẹsin igbagbọ ni wọn bi Duro si, sibẹ, o nifẹ si awọn ohun asa isẹnbaye gẹgẹ bi baba rẹ agba ti n se. Nigba to wa ni ọmọde, o maa n yọ yẹlẹkẹlẹ kuro ni ile alufa to wa ninu ọgba sọọsi, lati lọ wo iran egungun ati awọn ajọdun orisa miran ti wọn n se nigba naa
 • Duro Ladipọ lo bẹrẹ lilo awọn ilu isẹnbaye ninu ijọ ọmọlẹyin Kristi, ti wọn si le kuro ninu ijọ nitori wọn ri iwa yii gẹgẹ bii eewọ nla, amọ lati akoko naa, asa yii ko parun, ti wọn si n lo ilu abalaye lasiko ọdun Keresi. Duro Ladipọ si gba ami ẹyẹ latọwọ aarẹ Naijiria nigba naa, Ọmọwe Nnamdi Azikwe lasiko ọdun keresi kan to waye ni ibudo iko nkan isẹnbaye lọjọ si to wa ni Onikan, nilu Eko
 • Ifẹ to ni si asa isẹmbaye yii si lo tii titi de idi tiata, ti ọpọ ere rẹ naa si maa n se agbelarugẹ awọn ohun ajogunba wa nilẹ Kaarọ oojire
 • Lẹyin ti Duro Ladipọ ka iwe tan nilu Osogbo, lo wa si Ibadan, lati se isẹ Olukọ lọdun 1960, to si ti idi isẹ olukọ dara pọ mọ ẹgbẹ osere tiata Mbari Mbayọ pẹlu iranlọwọ oyinbo alawọ funfun kan lati orilẹede Germany, Ulli Beier, ẹni to nifẹ si awọn ohun isẹnbaye. Amọ ko pẹ lẹyin naa, to fi pada silu Osogbo, to si da ẹgbẹ osere tiẹ silẹ lọdun 1961
 • Duro Ladipọ ni ẹbun orin kikọ ati ilu lilu, eyi to maa n se afihan wọn ninu ere rẹ, to fi mọ amulo owe pipa. Lara awọn ere tiata to si jẹ ki Duro Ladipọ di ilumọọka ni Ọba Moro eyi to se lọdun 1962, Ọba Koso ati Ọba Waja, ti wọn jade lọdun 1964, Mọremi, Suuru baba Iwa, Tanimowo Iku, Bode Wasinmi, Ajagun nla ati bẹẹ bẹẹ lọ
 • Duro Ladipọ lọ si ọpọ orilẹede jakejado agbaye lati se afihan ere ori itage rẹ. Lara awọn orilẹede ti Duro Ladipọ atawọn ọmọ ẹgbẹ osere rẹ lọ ni Amẹrika, Holland, France, Italy, Yugoslavia¸Iran, Belgium, Scotland, Swizerland ati bẹẹ bẹẹ lọ
 • Ọpọ ami ẹyẹ ni Duro Ladipọ gba ninu ere tiata lorilẹ ede Naijiria ati loke okun. Lara rẹ ni eyi to gba ni orilẹede Germany nibi ajọdun isẹ ọnati ilu Berlin lọdun 1964 ati ami ẹyẹ to gba ni ajọdun isẹ ọna Commonwealth lọdun 1965
 • Ere tiata mẹrindinlogoji ni Duro Ladipọ kọ, to si se jade, nigba to kọ ere mẹwa, to si ko awo ere mẹsan sita lori ẹrọ giramofonu, to si se ere fiimu mẹrin
 • Lara awọn osere tiata ti wọn jẹ akẹẹgbẹ Duro Ladipọ ni Kọla Ogunmọla, Ọla Rotimi, Herbert Ogunde, Ayox Arisekọla, Ojo Ladipọ, Moses Ọlaiya Adejumọ ( Baba Sala), Oyin Adejọbi, Isọla Ogunsọla ( I show pepper) ati bẹẹ bẹẹ lọ
 • Duro Ladipọ ni ọpọ iyawo, to si tun bi ọmọ pupọ, amọ eyi to jẹ aayo ninu awọn iyawo rẹ ti gbogbo aye mọ ni Mama Abiọdun Duro Ladipọ, to maa n se ere Ọya, nigba ti Duro ba se Sango
 • Ọjọ nla ni ọjọ Kọkanla, osu Kẹta ọdun 1978 ti Duro Ladipọ mi kanlẹ, to si ki aye pe o digbose
 • Gẹgẹ bii orisa Sango ti gbogbo eeyan mọ si, apẹẹrẹ Sango lo jẹyọ lọjọ ti Duro Ladipọ jade laye, nitori ojo nla, to mu ara lọwọ lo rọ lọjọ naa, ti ara si n sana gidigidi. Asiko ojo ati ara nla yii na si ni Duro Ladipọ mi kanlẹ, ti akukọ si kọ lẹyin ọmọkunrin rẹ.

Duro Ladipọ̀ ti wa sile aye, to si ti lọ amọ̀ ko kọ̀ja nile aye gẹgẹ bii ejo to kọja lori apata, ti ko ni ipa kankan.

Image copyright Yomi Duro Ladipo

Kii kuku se pe Duro Ladipọ ka iwe rẹpẹtẹ ko to se aseyọri, amọ o lo ẹbun atinuda ti Ọlọrun fun lati ta ara rẹ yọ, to si di ilumọọka lawujọ agbanla aye.

Ki ni awọn talẹnti ti iwọ naa ro pe o ni? bawo lo si se lee lo talẹnti naa fun agbega iran rẹ, ti orukọ rẹ ko si ni di igbagbe?

Image copyright Yomi Duro Ladipo

Eyi lo yẹ ko jẹ ibeere ti yoo jẹ wa logun, ka si lọ se awari talẹnti wa gẹgẹ bi Duro Ladipọ ti se, kawa naa le wọ inu iwe itan manigbagbe.