Màmà àgbà yìí sunkún àwọn tó kú nínú ìjàmbá bàálù Ethiopia
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Ethiopia Airlines ET302: Obìnrin yìí ṣì ń ṣèdárò àwọn tó kú nínú ìjàmbá bàálù Ethiopia

Obinrin ọmọ orilẹede Ethiopia yii, Mulunesh Bejiga gbọ ariwo ki baalu ET302 to ja si ẹgbẹ ile rẹ.

Lati igba yii lo ti n ṣedaro pẹlu awọn ẹbi awọn eeyan to ku ninu ijamba baalu ọhun nigba kuugba ti wọn ba wa sibi ti baalu naa ja si.

Eeyan mẹtadinlọgọjọ lati orilẹdede marundinlogoji lo padanu ẹmi wọn ninu ijamba baalu naa to ṣẹlẹ nigba ti wọn n rinrin ajo lati ilu Addis Ababa lọ si ilu Nairobi.

O sọ pe ibanujẹ nla ni lati ri bi baalu ṣe ja ti ọpọ ẹmi si ṣofo.