Omotola Jalade-Ekeinde: Olùrànlọ́wọ́ Ààrẹ Buhari fèsì sọ́rọ̀ Omotola

Muhammadu Buhari ati Jalade Omotola Ekeinde

Oríṣun àwòrán, Facebook/Omotola

Ọgọrọ eeyan lori ayelujara lo ti n fesi sọrọ ti oṣere tiata Nollywood, Omotola Jalade-Ekeinde sọ nipa ijọba Aarẹ Muhammadu Buhari.

Omotola loju opo Twitter rẹ pe, orilẹede Naijiria dabi ọrun apaadi labẹ iṣejọba Aarẹ Buhari ati igbakeji rẹ, Ọjọgbọn Yemi Osinbajo.

Omotola wa kesi Aarẹ Buhari lati wa nnkan ṣe si airowo na to gbode kan ati awọn agbofinro ti wọn n pa awọn alaiṣẹ loorekoore ni kiakia.

O tẹsiwaju pẹlu ọrọ rẹ pe, ọrọ Naijiria ti kọja afarada bayii, o ni ibẹru bojo wa nibi gbogbo.

Ṣugbọn oluranlọwọ fun Aarẹ Buhari Bashir Ahmad fesi sọrọ Omotola, o ni ki o ye ṣaroye mọ nitori awọn ti wọn n ṣiṣẹ rowo lọna totọ ko ṣaroye, bẹẹ ni wọn ko si le sọ pe Naijiria da bi ọrun apaadi.

Ahmad ṣalaye pe laarin ọdun 2015 si 2018, aimọye biliọnu owo naira lo jade lati ilu Kano nikan nibi ọgbin irẹsi.

Sẹnẹtọ Shehu Sani kin ọrọ ti Omotola sọ lẹyin, o ni ohun ti ọpọ eeyan ti ko rọwọ họri n la kọ ja ni Omotola sọ jade.

Sẹnẹtọ Sani sọ pe eebu ti ọpọ n bu Omotola ko yi otitọ ọrọ ti o ti sọ pada.

Ọgbẹni J.J. Omojuwa ni tirẹ sọ pe, aisowo nilu ko sọ pe owo ti awọn kan fọna eru ko jọ ko si niluu, ṣugbọn anfani lati ri owo fun gbogbo eeyan ni ko si.

Omojuwa ni iṣorọ to n koju orilẹede Naijiria ko to lati di ẹbi rẹ ru ẹnikan.

Ninu ọrọ tiẹ, ajafẹtọ ọmọniyan, Deji Adeyanju ni, kii ṣe oni ni Omotola bẹrẹ si sọ otitọ. O ni gbajugbaja oṣere yii koju aarẹ ana to doloogbe Umaru Yar'ardua gan an.

Minisita tẹlẹ ri, Obi Ezekwesili ntiẹ́ rọ Omotola pe ko maa da awọn ti wọn n buu lohun. O ni aimoye lo da awọn ti wọn sọrọ sii laamu.

Ezekwesili sọ pe, Omotola lẹtọ lati sọrọ lori ohun ti ko ba tẹ lọrun gẹgẹ ọmọ Naijiria, bẹẹ lo rọ awọn ti wọn n sọrọ kobakungbe sii lati sọrọ ti wọn naa.

Ọgbẹni Reno Omokiri naa sọrọ, o ni idunkoko mọ Omotola pẹlu owo ori sisan ko ba ilana ijọba awarawa mu.

Omotola ni igbogun ti iwa ajẹbanu lawujọ ṣe pataki ṣugbọn ijọba gbọdọ rii wi pe awọn ọmọ Naijiria gbaye gbadun. O ni iṣẹ ijọba ni lati ṣejọba lọna ti yoo fi rọ ara ilu lọrun.

O fikun ọrọ pe, iru nnkan to mu ki orilẹede Amẹrika se ayipada ofin rẹ leyi, lati le ri pe awọn ọmọ orilẹede naa wa lailewu.

Omotola wa pari ọrọ rẹ bayii loju opo Twitter, nigba ti o ki gbogbo awọn eeyan ti wọn ti dasi ọrọ naa. O ni ẹbi kan naa ni gbogbo ọmọ Naijiria, ko si si ọta kankan laarin wọn.

O ni aifimọsọkan ni ọta to wa lorilẹede Naijiria, o si rọ awọn adari ijọba Naijiria pe ki wọn gbọ ohun tawọn eeayan n wi.