Ibe Kachikwu: Ọ̀nà àbáyọ sí èlé owó epo ni àtúnṣeàwọn ibùdó ìfọpo wa

Epo bentirol

Oríṣun àwòrán, Google

Minisita fun ọrọ to niise pẹlu bẹntirolu, Ibe Kachikwu ni Naira marundinlogoji lo ti gun iye owo ti lita epo bẹntirol n ba wọ orilẹede Naijiria.

Ibe Kachikwu sọ eyi lasiko to n sọrọ lori eto ‘Good Morning Nigeria’ ni ile isẹ Iroyin NTA lori ero ijọba lati yọ owo iranwọ ti ijọba n san lori epo bẹntirol.

Kachikwu ni ọwọngogo epo ati iye ti wọn n ra epo lagbaye to lọ soke, lo fa ọwọngogo epo bẹntirol ni ọdun 2016, ki o to di wi pe wọn tun bẹrẹ si ni san owo iranwọ epo.

Àkọlé fídíò,

'Èmi ò kí ń lu ìyàwó mi'

O fi kun wi pe, awọn gbọdọ fi ọgbọn se e ni, ti awọn ba setan lati yọ owo iranwọ ti ijọba n san lori epo bẹntirol nitori owo naa ti pọju fun ijọba lati ma a san ati wi pe owo ohun ti posi ba yii.

Ninu ọrọ minisita fun ọrọ epo bẹntirol naa, o ni oun to ba ni ninu jẹ ni wi pe, ti awọn ba yọ owo iranwọ, gbogbo awọn osisẹ ni yoo da isẹ silẹ , eleyii ti yoo ni ipa buburu lori ọrọ aje orilẹede Naijiria.

Kachikwu fikun wi pe, o se ni laanu wi pe awọn ti wọn n se karakata epo bẹntirol ko i tii gba gbogbo owo iranwọ ti ijọba n jẹ wọn.

Minisita naa wa ni ọna abayọ si ọrọ epo bẹntirol ni ki ile isẹ aladani gba isakoso karakata epo bẹntirol, ki ijọba si wa ọna abayọ kiakia lati tun gbogbo ile isẹ ibudo ifọpo to wa lorilẹede Naijiria se, ki wọn ye e dara le epo ti wọn n gbe wa lati ile okeere.