Oba Folagbade Olateru-Olagbegi wàjà lẹ́ni ọdún 77

Oríṣun àwòrán, Google
Ọlọ́wọ̀ ti Ọ̀wọ̀, Oba Folagbade Olateru Olagbegi CFR ti darapọ mọ awọn baba nla rẹ lẹni ọdun mẹtadinlọgọrin.
Agba Amofin lorilẹede Naijiria(SAN ) ni Ọba Ọlagbẹgi darapọ mọ awọn baba nla rẹ ni Ọjọ kẹtadinlogun, Osu Kẹrin, ọdun 2019.
Osu Keji, Ọdun 1999 ni o gori itẹ baba rẹ, amọ ọdun 2003 ni o gba ọpa asẹ ni ọwọ gomina tẹlẹri ni ipinlẹ Ondo, Olusegun Agagu.
'Èmi ò kí ń lu ìyàwó mi'
Tani Ọba Oba Folagbade Olateru-Olagbegi III waja?
- Ọjọ kọkanlelogun, Osu Keji,ọdun 2019 ni o pe ogun ọdun ti Oba Folagbade Olateru-Olagbegi III gun ori itẹ baba rẹ.
- Ọjọ Kẹrindinlọgbọn, Osu kẹfa ọdun 1941 ni won bi Ọlọwọ ti ilu Ọwọ to doloogbe gẹgẹ bi akọbi Sir Olateru Olagbegi (1910-1998).
- O kọ imọ ofin ni ilu London, ni Ilẹ Gẹẹsi, ti o si lọ ile iwe awọn agbejọrọ ni orilẹede Naijiria ni ọdun 1968.
- Asiko to n sisẹ ni ile iwe awọn agbẹjọro ni Naijiria ni o fẹ iyawo rẹ, Bisi Cole, ti wọn si bi ọmọ mẹrin.
- Ni ọdun 2005 ni wọn yan an gẹgẹbi Chancelor ile iwe giga fasiti ti ilu Abuja.
- Bakan naa, ohun ni Chancellor Ile Iwe giga fasiti Jos.
- Folagbade Olateru Olagbeji ni Alaga Tẹlẹ̀ri fun Ajọ Lọbalọba ni ipinlẹ Ondo.