Jega: Àwọn olùkọ́ fásitì sisẹ́ fáwọn olóṣèlú láti sèrú ìbò

Ọjọgbọn Attahiru Jega

Oríṣun àwòrán, @Prof_AJega

Alaga tẹlẹ fun ajọ eleto idibo nilẹ wa, Ọjọgbọn Attahiru Jega ti n naka aleebu sawọn olukọ ileẹkọ fasiti nilẹ wa pe awọn ni igi wọrọkọ to n da ina ru, nidi eto idibo ta sẹsẹ di ksja yii.

Jega salaye pe ọpọ awọn olukọ fasiti yii ni wsn lẹdi apo pọ mọ awọn oloselu lati se mago mago eto idibo to kọja.

Attahiru jega kede ọrọ yii lasiko ipade apero ẹgbẹ kan nilẹ Naijiria, ikẹẹdogun iru rẹ, eyi to waye nile ẹkọ fasiti Bayero nilu Kano.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Jega salaye pe awọn oloselu kan nipinlẹ Kano gan tiẹ lo awọn olukọ fasiti ọhun lati se ọpọ aise deede lasiko eto idibo 2019 to kọja yii.

Alaga tẹlẹ fun ajọ INEC naa ni "o dabi ẹni pe a ko mu ipe wa gẹgẹ bii ẹni to ni imọ ati ẹkọ to yẹ ni ọkunkundun, emi ko si mọ boya awọn eeyan to ti yipada ni mo n ba sọrọ abi mo kan n sọ isọkusọ ni"

Jega wa fikun pe orilẹede Naijiria ko ni bọ lọwọ awọn isoro ọrọ aje, aifararọ eto aabo ati aisi idagbasoke to yẹ, ti a ko ba sa ipa wa bo ti yẹ lati yan asaaju to kaato si ipo lati maa dari wa.

"O dabi ẹnipe isoro kan gboogi to n mi naijiria logbologbo ni eto idibo wa to mẹhẹ, eyi tawọn eeyan ti eto naa wa nikawọ wọn ti se siba-sibo."

Àkọlé fídíò,

JAMB 2019: A ó fagi lé ìdànwò ẹni tó bá ṣe aṣemáṣe

O wa rawọ ẹbẹ si gbogbo ọmọ Naijiria lati mase maa fi ọwọ yẹpẹrẹ mu awọn ohun to ba jẹ mọ iyansipo awọn asaaju wa nitori idi ilana yii ni ọrọ wa ti wọ.