Malabu Oil Scandal: Iléẹjọ́ ní kí àwọn ọlọ́pàá, Interpol gbé wọn níbikíbi tí wọn bá wà

Ibudo ifọ̀po kan

Oríṣun àwòrán, @Shell

Adajọ D.Zsenchi, lasiko to n gba ẹbẹ agbẹjọro ajọ EFCC to gbe ẹsun naa wa siwaju rẹ, salaye pe ibikibi ti wọn ba ti kofiri awọn afurasi naa ni ki wọn ti di wọn ni apanyaka boya lorilẹede yii ni abi loke okun.

Lara awọn afurasi tile ẹjọ ni ki wọn gbe ni tipa tikuuku lori ọrọ epo Malabu ni minisita fọrọ epo rọbi nigbakan, Dan Etete, Adajọ ati agbẹjọro agba tẹlẹ fun ilẹ wa, Mohammed Adoke pẹlu awọn eeyan miran ti wọn fi ẹsun kan pe ọwọ wọn ko mọ nidi katakara ibudo epo Malabu.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Awọn afurasi naa ni agbẹjọro ajọ EFCC, salaye pe wọn n sa nile ẹjọ lati igba ti ẹjọ naa ti bẹrẹ ni ọdun 2017 ti ajọ̀ naa ti n ba ileepo Shell, Eni Spa atawọ̀n yoku se ẹ́jọ̀.

Awọn yoku ti ọrọ naa kan ni Raph Wetzels, Casula Roberto, Pujato Stefeno, ati Burrato Sebastiano, ti wọn si gbe wọn lọ siwaju adajọ Senchi lọjọru oni, lori ẹsun pe wọn kọ lati wa yọju lori ẹsun ti wọn fi kan wọn naa.

Àkọlé fídíò,

'Èmi ò kí ń lu ìyàwó mi'

Nibi igbẹjọ to waye loni naa ni adajọ Senchi ti gbọ adura ajọ EFCC, to si ni ki wọn lọ di awọn eeyan naa wa sile ẹjọ ni tipa tipa, to si sun igbẹjọ ọhun siwaju di ọjọ Kọkanla osu Keje ọdun 2019.

Ileẹjọ giga to kalẹ si Jabi nilu Abuja ti pasẹ pe ki awọn ọlọpa lorilẹede Naijiria ati ajọ ọtẹlẹmuyẹ lagbaye lọ gbe awọn afurasi ti wọn fi ẹsun kan lori ẹsun ajẹbanu to nii se pẹlu ọrọ epo Malabu ti wọn ta nijooni.