Kenyan: Èyí ni bí wọ́n ṣe n lo Facebook lati ṣekupa awọn oníjàgídíjàgan

Obinrin ti wọn pa ọkọ rẹ meji

Ikọ kan ti wọn furasi pe o n sẹkupa awọn eniyan laarin awọn ọlọpaa orilẹ-ede Kenya, n lo Facebook lati mu ati lati pa awọn ọdọmọkunrin ti wọn gbagbọ pe wọn jẹ ọmọ ẹgbẹ onijagidijagan.

"Ọkọ meji ni mo ti padanu laarin ọdun kan,'' ni arabinrin kan sọ, t'ohun ti omije loju fun awọn araalu to pejọ sibi ipade kan to waye niluu Kayole loṣu Kẹta.

Bakan naa ni awọn miran naa tun sọ ẹri wọn, to farajọ ti ọdọmọbinrin naa.

Gbogbo wọn lo sọ pe awọn ti padanu awọn mọlẹbi, ti ọjọ ori wọn wa laarin ọdun mẹẹdogun si mẹrinlelogun.

Gẹgẹ bi ohun ti aṣoju oṣiṣẹ ajọ ajafẹtọ ọmọniyan kan, Wilfred Olal, ti ajọ Dandora Community Justice Centre sọ nibi ipade naa.

Ohun ti awọn apaniyan naa kọkọ maa n ṣe ni pe, wọn yoo fi orukọ ati aworan wọn sita lori Facebook gẹgẹ bi ọdaran.

Lẹyin naa ni wọn yoo yinbọn pa wọn lẹyin ọsẹ kan tabi oṣu kan.

Wọn yoo si fi aworan oku wọn sori Facebook bakan naa.

Oríṣun àwòrán, Facebook/Mwani Sparta

Àkọlé àwòrán,

Mwani Sparta fi aworan ara rẹ sori facebook pẹlu ibọn lọwọ pẹlu awọn ọmọ ẹgbẹ Gaza yoku

Awọn aworan naa maa n fi oju ibi ti ibọn ti ba wọn han; bi agbari to fọ, ifun to tu jade, pẹlu ikilọ pe ohun ti yoo ṣẹlẹ si awọn ọdaran to ku naa niyẹn.

Ọpọlọpọ ọdọ lo n darapọ mọ ẹgbẹ naa lati le mọ boya wọn fi orukọ wọn sita. Awọn to ba ri orukọ wọn si n sa fi agbegbe naa silẹ.

Oríṣun àwòrán, Facebook/Nairobi Crime Free

Àkọlé àwòrán,

Oju opo ẹgbẹ́ naa nibi ti wọn ti n ṣe ayẹwo fun awọn ọmọ ẹgbẹ́ tuntun

Awọn olugbe ilu Kayole sọ pe, oriṣiriṣi ẹgbẹ naa lo wa lori Facebook, ti wọn si maa n fi awọn aworan to banilọkan jẹ sibẹ lojoojumọ.

Kini awijare ileeṣẹ ọlọpaa?

Oluwadi kan ni Fasiti Moi ni Kenya, to n tọ pinpin awọn ẹgbẹ naa lori Facebook fun ọdun mẹta, Duncan Omanga, sọ pe, 'awọn ọlọpaa ti wọn furasi maa n gba ọna ẹburu lati ṣewadi awọn ti wọn fẹ ẹ pa lori ayelujara.

Igbesẹ wọn naa si maa n mu ko dabi ẹnipe oju awọn ọlọpaa to ibi gbogbo ni awọn agbegbe naa ni Kenya.

Amọ ṣa, ọga agba ileeṣẹ ọlọpaa Kenya nigba kan sọ pe, ẹni to wa nidi awọn ẹgbẹ naa lori Facebook kii ṣe ọlọpaa, ṣugbọn araalu ti ọrọ aabo ilu ka lara ni.

Àkọlé fídíò,

Ẹ̀mí kan náà ló n darí ìrìnàjò wa táa fi jọ kọ́lé papọ̀- Ìbejì

Igbagbọ awọn kan ni pe, bi wọn ṣe n gbe awọn olowo ti wọn fura si pe wọn n ji owo ori lọ sile ẹjọ, naa lo ṣe yẹ ki wọn maa fun awọn ọdọ naa ni anfaaani lati sọ awijare wọn lori ẹsun ti wọn ba fikan wọn.