Alan García: Ààrẹ Peru nígbà kan gbẹ̀mí ara rẹ̀

Alan Gracía

Oríṣun àwòrán, AFP

Àkọlé àwòrán,

Wọn fi ẹsun kan García pe o gba owo ẹyin lọwọ ileeṣẹ abanikọle kan to jẹ ti Brazil.

Aarẹ orilẹede Peru nigba kan, Alan García ti gbẹmi mi lẹyin to yinbọn mọ ara rẹ lasiko ti awọn ọlọpaa de si ile rẹ lati mu u fun ẹsun riba gbigba.

Ọgbẹni García ti wọn sare gbe lọ sileewosan ni olu ilu orilẹede naa, ko to o di pe o jade laye.

Aarẹ orilẹede naa lọwọlọwọ, Martin Vizcarra ti fidi iku rẹ mulẹ.

Wọn fi ẹsun kan García pe o gba owo ẹyin lọwọ ileeṣẹ abanikọle kan to jẹ ti Brazil, Odebrecht - amọ o ni oun ko jẹbi ẹsun naa.

Minisita fun ọrọ abẹle, Carlos Morán sọ fun awọn akọroyin pe Ọgbẹni García tọrọ aaye lati pe ẹnikan lori ẹrọ ibanisọrọ nigba ti awọn ọlọpaa de ile rẹ, to si wọ inu yaara kan lọ.

Lẹyin iṣẹju diẹ ni ìró ibọn dun.

Eyi lo si mu ki awọn ọlọpaa ja ilẹkun yaara naa, ti wọn si ba Ọgbẹni Gracía to joko sori aga kan t'ohun ti ọgbẹ ọta ibọn ni ori rẹ.