Oluwatoyin Bayegun: Nígbà tí mo di gbájúgbajà tán ni mo bẹ̀rẹ̀ sinimá

Irin ajo ọjọ pipẹ ni ṣiṣe ere agbelewo eyi to ti wa lọkan mọlumọọka apanilẹrin Oluwatoyin Bayegun ti gbogbo eniyan mọ si Woli Arole.

Oluwatoyin jẹ ko di mimọ wi pe "ko si nkan ti ẹda alaye le da ẹ duro fun lati di nkan ti o fẹ di, bi o ba ṣaa ti le gbadura".

Owe ni Woli Arole fi ọrọ to wa loke yii pa nitori o mọ ohun ti o ti la kọja ninu irin ajo ere sinima o si mọ ohun ti awọn eniyan ti sọ si i.

Eyi wa tun ṣe gẹgẹ iha ti awọn eniyan maa n kọ si didi eniyan nla laye ari itanjẹ ti wọn maa n gbagbọ gẹgẹ bi Arole ṣe ṣalaye ẹ ninu ọrọ rẹ.

Ninu oṣu kẹrin ọdun 2019 ni Woli Arole bẹrẹ si ni ṣe agbejade ere agbelewo tuntun eyi ti o ko ọpọlọpọ gbajugbaja oṣere sinu ẹ.