Intersex: Abiyamọ ní dókítà kò leè sọ bóyá akọ ni ọmọ òun àbí abo

Dokita ati abiyamọ to bimọ to bimọ

Ni ile aye ta wa yii, akọ ati abo ni ẹda lee jẹ amọ ti iyalẹnu maa n wa, ta ba ri ẹnikan ti kii se akọ abi abo.

Ni ọpọ igba ni ọba oke maa nda ara to ba wu, ti yoo si mu ki eeyan kan ni oju ara ti ọkunrin ati obinrin papọ eyi ti awọn oloyinbo n pe ni 'Hermaphrodites'.

Bẹẹ ni ọrọ ri fun obinrin yii, Catherine (kii se orukọ rẹ gangan niyi), ẹni ti dokita ko fi ẹnu sọ boya ọkunrin lo bi abi obinrin lẹyin ọjọ marun un to ti bimọ,

amọ to fi ami ibeere si ori iwe to fi yẹ ko sọ iru ẹda ti ọmọ obinrin naa n se.

Nigba to dele, ni iya ọmọ tuntun ba pe aladugbo rẹ pe ko wa wo ọmọ oun, ko si sọ boya ọkunrin abi obinrin, sugbọn dipo ki aladugbo yii fọhun, n se lo gba Catherine ni imọran lati lọ sile iwosan.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Idi ree ti abiyamọ yii ati ọkọ rẹ fi morile ile iwosan ijọba kan ni ilu Nairobi, lorilẹ-ede Kenya, nibi ti wọn ti gbọ pe ọmọ to ni nkan ọkunrin ati obinrin ni wọn bi, ti dokita si gba wọn niyanju lati wa se isẹ abẹ, ki ọmọ naa le di ọkunrin nitori nkan ọkunrin to wa lara ọmọ naa lagbara ju ti obinrin lọ.

Àkọlé fídíò,

Osinbajo yẹ́ Woli Arole sí níbi ìṣíde "The Call"

Obinrin naa ni "Lati igba yii ni ọkọ mi ko ti fi owo ounjẹ silẹ fun mi mọ, to si n fa sẹyin lati ba mi sere tabi sọrọ. Nigba miran, yoo pariwo mọ mi pe ko si ọmọ to ni iru oju ara akọ ati abo bẹẹ ninu iran oun, yoo si dara ki n gbe ọmọ naa pada si ibi ti mo ti gbe wa."

"Ọkọ mi bẹrẹ si ni kan mi ni abuku, o ni asẹwo ni mi, to si n sọ fun mi pe oun kọ ni oun ni ọmọ naa, oun ko mọ ibi ti mo ti rii"

Catherine ni aye su oun, ti ọkan oun si daru. Idi ree ti oun fi ra oogun to n pa eku lati gbe majele jẹ, ki oun kuku ku danu.

O po oogun eku naa mọ ẹwa to fẹ jẹ, ko le pa ara rẹ ati ọmọ tuntun naa, sugbọn nigba to ku diẹ ko gbe oogun naa jẹ, lo ba yi ọọkan rk pada, to si gba ile ijọsin kan lọ lati lọ ri Olusọaguntan ibẹ.

"Pasitọ naa fi mi lọkan balẹ pe Ọlọrun wa pẹlu mi, ti ko si fi mi silẹ ninu wahala naa, ati pe a ko ri iru eyi ri, ẹru la n da ba ọlọrọ.

Pasitọ ni kii se iru ọmọ mi nikan lo wa ni agbaye, iru awọn eeyan to ni nkan ọkunrin ati obinrin sun janti rẹrẹ, kii si se iwa ẹsẹ mi lo mu ki n bi ọmọ naa."

Inu wahala yii ni obinrin ti ko jade kuro nile ọkọ rẹ lẹyin osu kan pere to bimọ, to si n lọ gbe lọdọ ẹgbọn rẹ obinrin kan pẹlu ọmọ rẹ laisi owo kankan ti yoo fi tọju ọmọ ọhun.

Catherine wa isẹ se ni ile itọju ọmọ wẹwẹ, to si pinnu lati wa owo fun isẹ abẹ ọmọ naa, ni awọn isoro miran ba tun yọju lẹyin ọdun kan.

Àkọlé fídíò,

Olusegun Obasanjo: Ọmú ìyá mi ti mo fi ń mùkọ ni kekere ló jẹ ki ń lókun

Isoro akọkọ ni pe ko lee fi ọmọ naa sile iwe nitori pe ko mọ boya ọkunrin ni ki oun pe abi obinrin, bẹẹ ni iwe ọjọ ibi to yẹ ko mu silẹ, ni dokita to gbẹ bi rẹ ti fi ami ibeere siwaju alafo ti wọn ti fẹ mọ boya ọkunrin ni ọmọ naa abi obinrin.

Se oriire ni gbe alawore ko ni, asiko yii ni Catherine pade agbẹjọro ajafẹtọ ẹni kan, John Chigiti, ẹni to gbe ọrọ yii lọ sile ẹjọ.

Lẹyin ọdun marun, adajọ gba ẹbẹ agbẹjọro naa, to si dajọ pe:

  • Ki ile iwosan fun ọmọ Catherine to ti pe ọdun marun ni iwe ọjọ ibi
  • Ki agbẹjọro agba lorilẹ-ede Kenya se agbekalẹ igbimọ amusẹya kan ti yoo daba awọn ọna tawọn ọmọ to ni oju ara meji yoo fi maa gbe aye gbadun bii awọn eeyan yoku laisi idẹyẹ si kankan
  • Bakan naa ni ile ẹjọ ni ki wọn dawọ duro na lori sise isẹ abẹ fun ọmọ ọdun marun naa titi ti ọmọ naa yoo fi lee sọ boya nkan ọkunrin ni oun fẹ ni ni, abi ti obinrin.
  • Ileejọ tun ni ki se afikun abala ti yoo fun awọn eeyan to ni oju ara meji lanfaanin lati sọ irufẹ ẹda ti wọn jẹ.
  • Nigba ti M wa fun Male, eyiun ọkunrin, F wa fun Female, eyiun obinrin, abala I naa gbọdọ wa fun awọn eeyan to ni oju ara meji, eyi tii se Intersex.
Àkọlé fídíò,

East Africa: Àwọn kokoro ti ba èrè oko jẹ nílẹ̀ Afirika

  • Ile Ẹjọ naa tun ni awọn eeyan gbọdọ mọ awọn eeyan to ni oju ara meji bii ara isẹda, ti ko si gbọdọ si idẹyẹsi.
  • Ta ba ni ọkunrin, ati obinrin, awọn isẹda kẹta ti yoo wa ni awọn to ni oju ara meji.

Eyi ni isẹlẹ to waye ni Kenya, am nigba wo ni iru idajọ yii yoo waye ni Naijiria?