Ibadan Tanker Fire Accident: Ṣúnkẹrẹ fàkẹrẹ gbalẹ̀ lẹ́yìn ìjàmbá ọkọ̀ epo

Àkọlé fídíò,

Ibadan Tanker Fire Accident: Ènìyàn méji ló kú nínú ìjàmbá ọkọ̀ agbépo

Ẹni to ba jẹ ori ahun, yoo sunkun lọsan Ọjọbọ nilu Ibadan, nigbati ọkọ agbepo kan dede ṣubu ni agbegbe Sawmill-Iwo Road lopopona marosẹ Eko si Ibadan.

Ni dede aago meji kọja iṣẹju diẹ lọsan ni iṣele naa ṣẹlẹ, eyi taa gbọ pe o mu ẹmi eeyan meji lọ, awọn eeyan mejeeji yii, ti wọn jẹ ọkunrin ati obinrin si lo jona ku egungun ninu ijamba naa.

Nitori isẹlẹ yii, se ni adugbo Iwo Road di pa, ti ọ̀pọ̀ ero si n fi ẹsẹ rin, nigba ti awọn ọlọkọ to n rin irin ajo bọ lati awọn ilu miran ha sinu sunkẹrẹ fakẹrẹ ọkọ fun ọpọ wakati, ti ohun gbogbo si dẹnu kọlẹ lagbegbe naa. Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Oṣojumi-koro kan fi to awọn BBC Yoruba leti wi pe jala epo bii ẹgbẹrun marundinlaadọta ni ọkọ epo naa gbe, ki o to dede ṣubu laarin ọna.

Ọgbẹni Adeleke Isiaka, ti o jẹ aṣoju ajọ panapana ipinlẹ Ọyọ fi ẹsun kan wi pe, awọn alaigbọran kan to sare lati gbọn epo bentiro to n jo danu pẹlu oniruuru ohun elo ipọnmi, lo ṣokunfa iṣẹlẹ naa.

Adeleke fi kun ọrọ rẹ wi pe ẹmi eeyan meji ọtọọtọ (ọkunrin kan ati obinrin kan) lo ba iṣẹlẹ naa lọ.

Nibayii, igbokegbodo ọkọ ti bẹrẹ pada ni opopona naa, lẹhin ti wọn bomi pa ina ọhun, ti awọn ẹṣọ abo oju popo si n se akoso awọn ọkọ to n lọ to n bọ lagbegbe naa.