Onnoghen: CCT ní Onnoghen kò gbọdọ̀ di ipò ìlú mú fún ọdún mẹ́wà

Adajọ agba Walter Onnoghen

Oríṣun àwòrán, Nigeria Bar association

Àkọlé àwòrán,

Adajọ agba Onnoghen ni oun ko jẹbi

Igbimọ to n gbọ ẹsun to ni i ṣe pẹlu ihuwasi lawujọ, CCT ti sọ pe, lootọ ni adajọ agba Naijiria nigba kan, Walter Onnoghen, jẹbi ẹsun ṣiṣe mago-mago ninu dukia rẹ to kede.

Onnoghen n koju iwadi nitori ẹsun ti wọ̀n fi kan an pe o parọ́ ninu dukia to kede pe oun ni gẹgẹ bi adajọ agba orilẹede Naijiria.

Igbimọ ẹlẹni mẹta naa tun sọ pe, Onnoghen ko gbọdọ di ipo ilu kankan mu fun ọdun mẹwaa, ati pe ko gbagbe gbogbo owo to ni si apo aṣunwọn maarun nileefowopamọ.

Wọn ni owo naa ti di ti ijọba apapọ Naijiria.

Bakan naa ni alaga igbimọ naa, Danladi Umar to ka idajọ sita sọ pe ki Onnoghen fi ipo rẹ gẹgẹ bi alaga Igbimọ Idajọ ni Naijiria, CJN, to fi mọ Alaga ajọ to n mojuto ọrọ awọn oṣiṣẹ lẹka idajọ.