Minimum Wage: Ààrẹ Buhari ti buwọ́lu #30,000 owó oṣù òsìsẹ́

Aworan owo

Oríṣun àwòrán, PIUS UTOMI EKPEI

Àkọlé àwòrán,

Iye owo oṣu oṣiṣẹ́ jẹ nnkan ti o n kọ ọpọ oṣiṣẹ lominu ni Naijiria

Aarẹ Muhammadu Buhari ti buwọlu eto owo oṣu tuntun fun awọn oṣiṣẹ ijọba.

Awọn ileeṣẹ iroyin l'abẹle jabọ pe l'oni ọjọ kejidinlogun oṣu Kẹrin ni Aarẹ Buhari buwọlu ofin naa lati maa san ọgbọn ẹgbẹrun Naira gẹgẹ bi owo oṣu to kere ju fun oṣiṣẹ.

Tẹ ẹ ba gbagbe, oṣu Kẹta ọdun 2019 ni ile aṣofin agba buwọlu owo naa ti ijọba apapọ ati ti ipinlẹ gbọdọ maa san fun awọn oṣiṣẹ wọn.

Eyi waye lẹyin ti igbimọ to jiroro lori ọrọ naa gbe abọ ijiroro rẹ sita.

Botilẹjẹ wi pe ẹgbẹrun mẹtadinlọgbọn ni igbimọ naa gba ijọba niyanju lati maa san, ọgbọn ẹgbẹrun Naira ni awọn aṣofin fi ọwọ si.