Minimum wage tuntun kò túmọ̀ sí pé #30,000 ni yóò gun owó oṣù rẹ - Bismark Rewane

Aworan awọn oṣiṣẹ

Oríṣun àwòrán, NLC

Àkọlé àwòrán,

Aworan awọn oṣiṣẹ

Alaga igbimọ amusẹya to gba ijọba apapọ Naijiria nimọran lori ọna ti wọn yoo gba sanwo oṣu tuntun fun awọn oṣiṣẹ, Bismark Rewane, sọ pe kii ṣe gbogbo owo ti oṣiṣẹ n gba ni ẹkunwo naa yoo ba.

O ṣalaye pe kii ṣe gbogbo eniyan ni ẹgbẹrun lọna ọgbọn Naira naa yoo kan.

''Awọn ti owo oṣu wọn ju ẹgbẹrun lọna ọgbọn Naira lọwọlọwọ yoo kan gba ẹkunwo kekere ni.''

Fun apẹẹrẹ, lọdun 2011, gbogbo oṣiṣẹ ijọba to n gba ju ẹgbẹrun mejidinlogun Naira lọ gba ẹkunwo ẹẹdẹgbẹrun Naira pere.''

Ṣugbọn nigba ti akọroyin BBC beere lọwọ rẹ pe eelo ni ẹkunwo kekere ti yoo gun ori owo oṣu, o kọ̀ lati sọrọ.

Rewane tẹsiwaju ninu àlàyé naa pe, ilana ti igbimọ gba ni lati sọ owo oṣu gbogbo awọn ti ko to ẹgbẹrun lọna ọgbọn Naira si ẹgbẹrun lọna ọgbọn Naira. ''Ṣugbọ̀n ijọba apapọ ati ipinlẹ ni ilana ọtọọtọ ti wọn yoo gbe e gba.''

Oríṣun àwòrán, Presidency

Àkọlé àwòrán,

Onimọ nipa eto ọrọ-aje ati owo nina ni Ọgbẹni Bismark Rewane

Bakan naa ni Ọgbẹni Rewane sọ pe lootọ lo ṣeeṣe ki owo gun iye ti wọn n ta awọn nkan l'ọja, amọ ko ni ni ipa ti ko dara lara owo to n wọ apo oṣiṣẹ.

Ati wi pe awọn anfaani tuntun ninu eto ọrọ-aje ti igbimọ naa tọka si fun ijọba apapọ tumọ si pe owo yoo pọ si niluu.

Aarẹ Buhari lasiko to bu ọwọ lu owo oṣu tuntun naa l'Ọjọbọ ṣalaye nipasẹ oluranlọwọ rẹ lori ọrọ ile aṣofin apapọ, Ita Enang, pe l'oju ẹsẹ ni sisan owo oṣu tuntun naa bẹrẹ.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ọgbẹni Enang sọ fun awọn oniroyin pe awọn ti ko ni ju oṣiṣẹ mẹẹdọgbọn lọ nikan ni owo oṣu tuntun naa yọ silẹ.

Fun awọn ipinlẹ, Ọgbẹni Rewane sọ pe "ilana ti igbimọ naa gbe igbesẹ naa gba yoo mu ko rọrun fun wọ̀n lati sanwo naa ju ijọba apapọ lọ, ti wọn ba le naa owo wọn pẹlu eto to yẹ."

O ni ohun to da oun l'oju ni pe orilẹede Naijiria yoo dun n gbe ti ijọba ba le tẹle awọn nkan ti igbimọ amuṣẹya naa gba a nimọran.