Helen Paul: Bí o kò bá fẹ́ kí wọ́n mọ ìrírí rẹ, òun pa ẹlòmíì lára

Helen Paul: Bí o kò bá fẹ́ kí wọ́n mọ ìrírí rẹ, òun pa ẹlòmíì lára
Helen Paul

Oríṣun àwòrán, itshelenpaul

Àkọlé àwòrán,

Helen Paul

Apanilẹrin, olorin ati oṣere ni Helen Paul. Ẹlẹfẹ ori itage ti gbogbo eniyan mọ si Tattafo ni pẹlu ohun rẹ hẹrẹ hẹrẹ to bẹẹ ti a da bii pe ọmọde lo ń sọrọ.

Ninu oṣu kẹta ọdun 2019 ni Helen Paul gba oye PhD lati ile iwe giga fasiti ti ipinlẹ Eko. Lasiko yii kan naa lo tun fi sita han faraye pe ipasẹ ifipabanilopọ ni iya fi bi oun.

Nigba naa lo fi hande wi pe oun ko korira afipabanilopọ to jẹ baba oun to fipa ba iya rẹ lo pọ lọjọ kinni ana ṣugbọn o ni "mo ti dari ji baba mi" tori o ṣe ko ṣe, oun lo ṣe ọlọkọ to wa mi wa si aye.

Helen Paul ni itan yii ko tilẹ ki n ṣe itan oun gbọọn lati ilẹ bi ko ṣe itan iya to bi i lọmọ, iya yii kan naa lo wa fi oye PhD to gba ji fun.

Nitori naa, Helen ni oun ko kabamọ itan pe latara iṣẹlẹ ifipabanilopọ ni wọn ti bi oun. O ni "mo lo akoko yii lati fi fi oju itan ibi mi dan faraye nitori mo fi oye ile iwe giga ti mo gba yii ji iya mi"

Ninu ifọrọwanilẹnu wo pẹlu BBC Yoruba, Helen ṣalaye bi awọn ara adugbo ṣe n fi alebu yii wo o ṣugbọn o bori gbogbo rẹ o si tun nigbagbọ pe ilakọja naa ko tii tan o, oun a si bori ohun gbogbo.

Nigba to ti wa ṣe aṣeyọri bayii, o ri i bi anfani lati fi itan rẹ gba awọn to ba ni iru iriri ọmọ ti wọn fipa ba iya rẹ lo pọ tabi irufẹ iriri buruku mii bii tirẹ pe "ti o ba nii lọkan pe waa la, waala". Tori oun ko dede de ipo ti o wa bayii.

Eyi lo fi gba gbogbo ẹni to ba n la oniruuru iriri kọja lati mu ara wọn lọkan le ki wọn le bori.