Church Wall Collapse: Ògiri ṣọ́ọ̀ṣì wó pa àwọn olùjọ́sìn 13 nílé ìjọsìn South Afrika

Aworan apẹrẹ ile ijọsin to wo

Oríṣun àwòrán, AFP

Awọn olujọsin ẹlẹsin Kristẹni mẹtala kan ti padanu ẹmi wọn ni South Afrika.

Iṣẹlẹ yii waye nigba ti ogiri wo pa wọn nile ijọsin ti wọn ti n kopa ninu ijọsin ọjọ ọjọbọ mimọ rere lasiko ọdun ajinde.

Awọn oṣiṣẹ pajawiri ni eeyan mọkandilogun miiran lo farapa ti awọn si ti gbe wọn lọ si ile iwosan.

Awọn alaṣẹ lagbegbe KwaZulu Natal fi idi ọrọ yii mulẹ ti wọn si ni ojo arọda lagbegbe Empageni lo jọ bi ẹ ni ṣe okunfa bi ogiri ile ijọsin ijọ igbalode naa ti ṣe wo lulẹ.

Agbẹnusọ ile iṣẹ ọlọpaa KwaZulu Natal Thembeka Mbele sọ pe atẹgun ojo lile fẹ ni agbegbe naa lalẹ ọjọbọ.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Iroyin lati agbegbe naa so pe awọn eeyan kan n sun lọwọ nigba ti ogiri naa ya lu wọn.

Awọn olori ijọ ti ba awọn eeyan agbegbe naa kẹdun iṣẹlẹ laabi ọhun.