Leicester best player award: Iheanacho, Ndidi yóò jọ du àmì ẹ̀yẹ Leicester City

Ndidi ati Iheanacho

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Wọn ti fi orukọ ọmọ orilẹede Naijiria, Wilfred Ndidi ati Kelechi Iheanacho silẹ fun ami ẹyẹ agbabọọlu Leicester City to tayọ ju ni saa yi (Player of the Season).

Bakan naa ni wọn fi orukọ wọn silẹ fun ami ẹyẹ ọdọmọde agbabọọlu to tayọ (Young Player of the Season).

Orukọ Ndidi ati Iheanacho wa lara awọn ti wọn fi orukọ wọn silẹ lori itakun ayelujara ikọ agbabọọlu Leicester City fun ami ẹyẹ mejeeji.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Ndidi kopa ninu idije mẹrinlelọgbọn ni saa Premier League to n lọ lọwọ, to si gba bọọlu sinu awọn lẹẹmeji.

Ndidi ti gba ami ẹyẹ ọdọmọde agbabọọlu to dantọ julọ fun saa meji lẹyin to darapọ mọ Leicester lati KRC Genk ti Belgian Jupiler League.

O si ti kopa ninu idije mẹrinlelọgbọn ni saa Premier League to n lọ lọwọ, to si gba bọọlu sinu awọn lẹẹmeji.

Amọ ṣa, ko si eyi to wọ ipele ami ẹyẹ goolu to dara ju ni saa yii ninu awọn mejeeji.

Ni ti Iheanacho, o ti kopa ninu idije mejidinlọgbọn ni saa yii fun Leicester, o si gba bọọlu sinu awọn lẹẹkan ṣoṣo.

Awọn agbabọọlu mii yoo dije fun ami ẹyẹ 'Young Player of the Season' ni Demarai Gray, Harvey Barnes, Youri Tielemans, Ben Chilwell, James Maddison, Filip Benković, Çağlar Söyüncü ati Hamza Choudhury.

Nigba ti Daniel Amartey, Nampalys Mendy,Wes Morgan, Danny Simpson, Rachid Ghezzal, Shinji Okazaki, Harry Maguire, Filip Benković, Matty James, Ricardo Pereira, Adrien Silva ati Çağlar Söyüncü yoo dije fun ami ẹyẹ agbabọọlu to dara julọ ni saa yii.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Papa iṣere Leicester City, King Power ni gbigba ami ẹyẹ naa yoo ti waye

Bakan naa ni Hamza Choudhury, Youri Tielemans, Ben Chilwell, Demarai Gray, Marc Albrighton, Danny Ward, Harvey Barnes, Jamie Vardy, Andy King, Kasper Schmeichel, Christian Fuchs, Jonny Evans, Fousseni Diabaté ati James Maddison yoo kopa.

Ọjọ keje oṣu Karun ni wọn yoo kede awọn to jawe olubori ni papa iṣere King Power l'opin saa yii.