Tanko Muhammad: Ààrẹ Buhari fikún sàá Muhammad Tanko nípò adelé adájọ́ àgbà

Aa Buhari yan Tanko Ibrahim lati dele de adajọ Onnoghen

Oríṣun àwòrán, AsoRockVilla

Àkọlé àwòrán,

Aa Buhari yan Tanko Ibrahim lati dele de adajọ Onnoghen

Iroyin kan ti a ko ti i fi bẹẹ fi mulẹ sọ pe Aarẹ Muhammadu Buhari ti fi oṣu mẹta kun ọjọ to yẹ ki adele Adajọ Agba Naijiria, Tanko Muhammad lọ n'ipo.

Oluranlọwọ pataki fun Aarẹ Buhari lori ibaraẹnisọrọ igbalode, Bashir Ahmed loju opo Twitter rẹ fidi iroyin naa mulẹ.

Oṣu Kinni ọdun 2019 ni aarẹ yan Muhammad lẹyin to paṣẹ fun Adajọ Agba tẹlẹ, Walter Onnoghen lati lọ rọọkun nile nitori ẹsun ṣiṣe mago-mago lasiko to kede dukia rẹ gẹgẹ bi adajọ agba.

Ọjọ kejidinlogun oṣu Kẹrin si ni igbimọ to n gbọ ẹjọ naa, CCT, sọ pe o jẹbi ẹsun naa, ti wọn si fi ofin de e pe ko ma di ipo ilu mu fun ọdun mẹwaa.

Onnoghen sọ pe oun ko jẹbi.